A Ya Tẹmpili Kejì sí Mímọ́ (continued)

515 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 147–150

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,

ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!

2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;

Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.

3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn

ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.

4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀

ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.

5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára

òye rẹ̀ kò sì ní òpin.

6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa

fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀

ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé

ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè

9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko

àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin,

bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin

11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu;

yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára,

Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ

14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀,

òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.

16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn

ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú

17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́

ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀

18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀

ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́

ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu

àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.

20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀

wọn ko mọ òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

148:1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,

ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.

2 Ẹ fi ìyìn fún un,

gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

ẹ fi ìyìn fún un,

gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.

3 Ẹ fi ìyìn fún un,

oòrùn àti òṣùpá.

Ẹ fi ìyìn fún un,

gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

4 Ẹ fi ìyìn fún un,

ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga

àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa

nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé

ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá

ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi

àti ẹ̀yin ibú òkun,

8 mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín

ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,

ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

9 òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké,

igi eléso àti gbogbo igi kedari,

10 àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn

gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,

11 àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo

àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,

12 ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin

àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa

nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá

ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,

ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,

àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

149:1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.

Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

2 Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a

jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní

ayọ̀ nínú ọba wọn.

3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀

jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

4 Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀

ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

5 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀

kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

6 Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn

àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.

7 Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,

àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,

8 láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn

àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀

irin de àwọn ọlọ́lá wọn.

9 Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn

èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

150:1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀,

ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.

2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.

Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.

3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.

Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.

4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín

fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,

5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,

ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.