Gbígbé àpótí ẹ̀rí kúrò

1045 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 105

1  Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,

jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;

sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.

3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀,

jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;

wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,

ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6 ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,

ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:

ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

8  Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,

ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran,

9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,

ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ,

sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:

11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani

gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”

12 Nígbà tí wọn kéré níye,

wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀

13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,

láti ìjọba kan sí èkejì.

14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;

ó fi ọba bú nítorí tiwọn:

15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi; má sì ṣe wòlíì mi níbi.”

16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà

ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;

17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn

Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

18 Wọn fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀

a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin,

19 títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ

títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.

20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀

àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀

21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀,

aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,

22 gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa

ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé

kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23 Israẹli wá sí Ejibiti;

Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.

24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i

ó sì mú wọn lágbára jù

àwọn ọ̀tá wọn lọ

25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn

láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀,

àti Aaroni tí ó ti yàn.

27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn

ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.

28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú

wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

ó pa ẹja wọn.

30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,

èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,

ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn

32 Ó sọ òjò di yìnyín,

àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;

33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn

ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.

34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,

àti kòkòrò ní àìníye,

35 wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,

wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run.

36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,

ààyò gbogbo ipá wọn.

37 Ó mú Israẹli jáde

ti òun ti fàdákà àti wúrà,

nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,

nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,

àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́.

40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,

ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.

41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;

gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀

àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.

43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde

pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,

wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45 kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́

kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 96

1  Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,

ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀

ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.

3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;

òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.

5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè

ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.

6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀

agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn,

ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa.

8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;

ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.

9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;

ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.”

A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;

ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo

jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.

12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀;

nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀.

13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,

nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé

àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.