Gbígbé àpótí ẹ̀rí kúrò (continued)

1045 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 106

1  Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún

Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun,

nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

2 Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,

ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?

3 Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?

Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

4 Rántí mi, Olúwa,

nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,

wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,

5 kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,

kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,

ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

6 Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,

àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,

a sì ti hùwà búburú.

7 Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,

iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,

wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,

gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.

8 Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ

láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.

9 O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;

o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.

10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn,

láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.

11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn;

bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.

12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́

wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.

13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe

wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.

14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,

nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.

15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún

ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose

pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì

ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.

18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;

iná jo àwọn ènìyàn búburú.

19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù

wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.

20 Wọ́n pa ògo wọn dà

sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.

21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n

ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,

22 iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu

àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.

23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run

bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,

tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà

tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

24 Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà

wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.

25 Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn

wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.

26 Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè

kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,

27 láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè

láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.

28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,

wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,

29 wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe

àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.

30 Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,

àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán.

31 A sì ka èyí sí òdodo fún un àti

fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀

32 Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,

ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.

33 Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.

34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn run

gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,

35 Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,

wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.

36 Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn

tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.

37 Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ

àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.

38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ.

Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani,

ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.

39 Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,

wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀

ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀

41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,

àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.

42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú

wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,

síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i

wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro

nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn,

45 ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn

Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.

46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn

ó mú wọn rí àánú.

47  Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,

kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,

láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ

láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48 Olùbùkún ni Olúwa,

Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

2 Samuẹli 6:20–23

20 Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”

21 Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa. 22 Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”

23 Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.

1 Kronika 13:5–14

5 Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu. 6 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù gòkè wá.

7 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ. 8 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè.

9 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọsẹ̀. 10 Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

11 Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Peresi-Usa.

12 Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi? 13 Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. 14 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.