Ògo àti Ìṣẹ́gun Ìjọ ní Ọjọ́ Iwájú

710 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Isaiah 59:16–61:11

16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,

àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;

nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,

àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.

17  Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,

àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;

ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀

ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.

18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,

bẹ́ẹ̀ ni yóò san án

ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀

àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;

òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.

19  Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,

àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.

Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi

èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.

20  “Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,

sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó

ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé,” ni Olúwa wí.

60:1 “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,

ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.

2 Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé

òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,

ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́

ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.

3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,

àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

4 “Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò.

Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;

àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,

àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.

5 Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,

ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;

ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,

sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.

6  Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,

àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.

Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,

wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́

tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

7 Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,

àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́;

wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi,

bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

8 “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,

gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

9 Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;

ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;

mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,

pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,

fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,

Ẹni Mímọ́ Israẹli,

nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ

àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,

ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.

11  Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,

a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,

tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó

ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá

tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.

12 Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;

pátápátá ni yóò sì dahoro.

13 “Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,

igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,

láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;

àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.

14  Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò

wá foríbalẹ̀ fún ọ;

gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ

wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,

Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,

Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé

àti ayọ̀ àtìrandíran.

16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè

a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.

Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa,

èmi ni Olùgbàlà rẹ,

Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.

17 Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,

dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,

àti irin dípò òkúta.

Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ

àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,

tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,

ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà

àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.

19 Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,

tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,

nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,

àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

20 Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,

àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;

Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,

àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

21 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo

àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.

Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,

iṣẹ́ ọwọ́ mi,

láti fi ọláńlá mi hàn.

22 Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún (1,000) kan,

èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.

Èmi ni Olúwa;

ní àkókò rẹ̀, Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”

61:1  Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi

nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí

láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.

Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́

láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn

àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

2 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa

àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,

láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni

láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,

òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,

àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.

A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,

irúgbìn Olúwa

láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́

wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;

wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà

tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;

àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,

a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.

Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè

àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

7 Dípò àbùkù wọn

àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,

àti dípò àbùkù wọn

wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;

bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,

ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.

8 “Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;

mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀.

Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn

èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.

9 A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn.

Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé

wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”

10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;

ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.

Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà

ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;

gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,

àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.

11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde

àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn

kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.