Ògo àti Ìṣẹ́gun Ìjọ ní Ọjọ́ Iwájú (continued)

710 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Isaiah 62–64

1 Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́,

nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu,

títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,

àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.

2  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ,

àti gbogbo ọba ògo rẹ

a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn

èyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un.

3 Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,

adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.

4 Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́

tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.

Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba,

àti ilẹ̀ rẹ ní Beula;

nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ

àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.

5 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó

Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.

6 Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu;

wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.

Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,

ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi,

7 àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi

títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀

tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.

8 Olúwa ti búra pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀

àti nípa agbára apá rẹ:

“Èmi kì yóò jẹ́ kí ìyẹ̀fun rẹ

di oúnjẹ fún ọ̀tá rẹ

bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnì

tuntun rẹ mọ́

èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;

9 ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́,

tí wọn ó sì yin Olúwa,

àti àwọn tí wọ́n bá kó àjàrà jọ ni wọn ó mú un,

nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”

10 Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!

Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.

Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó!

Ẹ ṣa òkúta kúrò.

Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè.

11 Olúwa ti ṣe ìkéde

títí dé òpin ilẹ̀ ayé:

“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,

‘Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!

Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,

àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”

12 A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,

ẹni ìràpadà Olúwa;

a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,

ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.

63:1  Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá,

ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá?

Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀,

tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?

“Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo

tí ó ní ipa láti gbàlà.”

2 Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa

gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?

3  “Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;

láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.

Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi

mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi

ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,

mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

4 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi

àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé.

5 Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.

Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;

nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi

àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.

6 Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;

nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu

mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”

7 Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa,

ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,

gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa,

bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo

tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli,

gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.

8 Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,

àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;

bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.

9 Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́

àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.

Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;

ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n

ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.

10 Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀

wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.

Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn

òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.

11  Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,

àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀

níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já,

pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?

Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán

Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,

12 ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀

láti wà ní apá ọ̀tún Mose,

ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn,

láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

13 ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?

Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀;

14 gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,

a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa.

Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín

láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.

15 Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i

láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.

Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?

Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a

ti mú kúrò níwájú wa.

16 Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá

tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe;

ìwọ, Olúwa ni Baba wa,

Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.

17 Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ

tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?

Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,

àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ.

18 Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ,

ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.

19 Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì;

ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jẹ ọba lé wọn lórí,

a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.

64:1 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,

tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

2 Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó

tí ó sì mú kí omi ó hó,

sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ

kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

3 Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,

o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.

4  Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí

kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,

kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,

tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

5 Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn

ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,

tí ó rántí ọ̀nà rẹ.

Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,

inú bí ọ.

Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?

6 Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,

gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;

gbogbo wa kákò bí ewé,

àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.

7 Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ

tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;

nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa

ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8 Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.

Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;

gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

9 Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa,

má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.

Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,

nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.

10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;

Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.

11 Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,

ni a ti fi iná sun,

àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.

12 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?

Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?