Ìjọba Israẹli

Ṣalamaneseri Gbógun Wọ Ìjọba Hosea

Ìṣàkóso Hosea, ọba Israẹli, tẹ̀síwájú. Ṣalamaneseri gbógun wọ àwọn ilẹ̀ Hosea.

ní nǹkan bí 725 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Ọba 17:3–4

3 Ṣalamaneseri ọba Asiria wá sókè láti mú Hosea, ẹni tí ó ti jẹ fún Ṣalamaneseri ó sì ti san owó òde fún un. 4 Ṣùgbọ́n ọba Asiria rí i wí pé Hosea jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ ọba Ejibiti, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Asiria, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọọdún. Nígbà náà ọba Asiria fi agbára mú ún, ó sì fi sínú túbú.

Hosea Sọ Ìgbèkùn Ẹ̀yà Mẹ́wàá Tẹ́lẹ̀ 725 ṣáájú ìbí Kristi

Hosea sọ ìgbèkùn ẹ̀yà mẹ́wàá tẹ́lẹ̀, ó sì rọ àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà.

Hosea 7–8

1 nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá.

Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn

ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta.

Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn,

àwọn olè ń fọ́ ilé;

àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;

2 ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé

mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn.

Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá;

wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.

3 “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,

àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn.

4 Alágbèrè ni gbogbo wọn

wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà

tí a dáwọ́ kíkoná dúró,

lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.

5 Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa

wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná

ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.

6 Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò

wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí,

ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru

ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.

7 Gbogbo wọn gbóná bí ààrò

wọ́n pa gbogbo olórí wọn run,

gbogbo ọba wọn si ṣubú

kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.

8 “Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;

Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.

9 Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run

ṣùgbọ́n kò sì mọ̀.

Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri

bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i.

10 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i

ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí

kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa

Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.

11 “Efraimu dàbí àdàbà

tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n

tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí

tó sì tún ń padà lọ si Asiria.

12 Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn,

Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run.

Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀,

Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.

13 Ègbé ní fún wọn,

nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!

Ìparun wà lórí wọn,

nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!

Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà.

Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.

14 Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,

ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn.

Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì

ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.

15 Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,

síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.

16 Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo;

wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́.

Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú

nítorí ìrunú ahọ́n wọn.

Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe

ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.

8:1 “Fi ìpè sí ẹnu rẹ!

Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa

nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,

wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.

2 Israẹli kígbe pè mí,

‘Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’

3 Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀

ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀.

4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi

wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀.

Wọ́n fi fàdákà àti wúrà

ṣe ère fún ara wọn,

si ìparun ara wọn.

5 Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria!

Ìbínú mi ń ru sí wọn:

yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?

6 Israẹli ni wọ́n ti wá!

Ère yìí agbẹ́gilére ló ṣe é,

àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.

7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́

wọ́n sì ká ìjì.

Igi ọkà kò lórí,

kò sì ní mú oúnjẹ wá.

Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà

àwọn àjèjì ni yóò jẹ.

8 A ti gbé Israẹli mì,

báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

bí ohun èlò tí kò wúlò.

9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria

gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.

Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè,

Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí.

Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù

lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.

11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀

gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un

12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn,

ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì.

13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,

wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀,

ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.

Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn

yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Wọn yóò padà sí Ejibiti.

14  Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀

Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀

Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀

ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan

sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”