Hosea Sọ Ìgbèkùn Ẹ̀yà Mẹ́wàá Tẹ́lẹ̀ (continued)

Hosea sọ ìgbèkùn ẹ̀yà mẹ́wàá tẹ́lẹ̀, ó sì rọ àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà.

725 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Hosea 9–11

1 Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;

má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.

Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè

ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.

2 Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ

wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀.

3 Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa

Efraimu yóò padà sí Ejibiti,

yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.

4 Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.

Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.

Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.

Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.

Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn

kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.

5 Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn

ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?

6 Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun

Ejibiti yóò kó wọn jọ,

Memfisi yóò sì sin wọ́n.

Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,

Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.

Ẹ̀gún yóò sì bo

gbogbo àgọ́ wọn.

7  Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;

àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé.

Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí.

Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀

ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.

A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀,

a ka ẹni ìmísí sí asínwín.

8 Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,

ni olùṣọ́ ọ Efraimu.

Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀

àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.

9 Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́

gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah

Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn

yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

10 “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.

Mo rí àwọn baba yín,

bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.

Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,

wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,

ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. 11 Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ

kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.

12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.

Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn.

Ègbé ni fún wọn,

nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!

13 Mo rí Efraimu bí ìlú Tire

tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára

ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn

ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”

14 Fún wọn, Olúwa!

Kí ni ìwọ yóò fún wọn?

Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́

àti ọyàn gbígbẹ.

15 “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali,

Mo kórìíra wọn níbẹ̀,

nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi,

Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́

ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.

16 Efraimu ti rẹ̀ dànù

gbogbo rẹ̀ sì ti rọ,

kò sì so èso.

Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.

Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”

17 Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀

nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i;

wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

10:1 Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀

ó ń so èso fún ara rẹ̀.

Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀

bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i

bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere

o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.

2 Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ

báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn.

Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀

yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.

3 Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba

nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa

ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,

kí ni yóò ṣe fún wa?”

4 Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,

wọ́n ṣe ìbúra èké,

wọ́n da májẹ̀mú;

báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,

bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.

5 Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù

nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni.

Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí

bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀.

Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀,

nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.

6 A ó gbé lọ sí Asiria

gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá

a ó dójútì Efraimu;

ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀.

7 Bí igi tó léfòó lórí omi ni

Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.

8  Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun,

èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli.

Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,

yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.

Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”

àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”

9 “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli,

ìwọ sì tún wà níbẹ̀.

Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi

ni Gibeah bá bí?

10 Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n;

Orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ, wọ́n ó sì dojúkọ wọn,

láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11 Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́,

to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà;

lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni

èmi ó dí ẹrù wúwo lé.

Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin

Juda yóò tú ilẹ̀,

Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.

12  Ẹ gbin òdòdó fún ara yín,

kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin.

Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro,

nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,

títí tí yóò fi dé,

tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

13 Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi,

ẹ ti jẹ èso èké

nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín

àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín,

14 ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín

kí gbogbo odi agbára yín ba le parun.

Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun,

nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.

15 Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli,

nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù.

Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà,

a o pa ọba Israẹli run pátápátá.

11:1  “Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀,

mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.

2 Bí a ti ń pe wọn,

bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi,

wọn rú ẹbọ sí Baali,

wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.

3 Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn

mo di wọ́n mú ní apá,

ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀

pé mo ti mú wọn láradá.

4 Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n

àti ìdè ìfẹ́.

Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn,

Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.

5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí.

Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí

nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?

6 Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn

yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́

yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.

7 Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi

bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ,

kò ní gbé wọn ga rárá.

8 “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu?

Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli?

Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma?

Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Seboimu?

Ọkàn mi yípadà nínú mi

àánú mi sì ru sókè.

9 Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ,

tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro.

Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn.

Ẹni mímọ́ láàrín yín,

Èmi kò ní í wá nínú ìbínú.

10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;

òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún.

Nígbà tó bá bú,

àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.

11 Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù

bí i ẹyẹ láti Ejibiti,

bí i àdàbà láti Asiria,

Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”

ni Olúwa wí.

12 Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká

ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn.

Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.