Àwọn Sáàmù nípa Gbígbé Àpótí Ẹ̀rí Wọ Tẹmpili Solomoni

1004 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 47

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn

ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.

2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó

ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa

àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa

4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa,

ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.

5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,

Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.

6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.

Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!

7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,

ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!

8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;

Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.

9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ

gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu

nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,

òun ni ó ga jùlọ.

Saamu 97–100

1 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀

jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.

2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká

òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3 Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.

4 Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé

ayé rí i ó sì wárìrì.

5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,

níwájú Olúwa gbogbo ayé.

6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

7  Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,

àwọn tí ń fi ère gbéraga,

ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

8 Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn

inú àwọn ilé Juda sì dùn,

nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.

9 Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ

ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.

10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́

Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́

ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo

àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.

12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,

kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

98:1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,

nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;

ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀

o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀

o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.

3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;

gbogbo òpin ayé ni ó ti rí

iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,

ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,

5 ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

6 pẹ̀lú ìpè àti fèrè

ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

7 Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo

ohun tí ó wà nínú rẹ̀,

Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,

ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;

9 ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa,

nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé

bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo

àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

99:1 Olúwa jẹ ọba;

jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì

Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù

jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.

2 Olúwa tóbi ní Sioni;

Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.

3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi

tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.

4 Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,

ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;

ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.

5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa

ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀

Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀

wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,

wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

8 Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;

ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli

ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n.

9 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa

kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀

nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.

Saamu. Fún ọpẹ́.

100:1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.

2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa,

ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,

kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé

tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀

àti àgùntàn pápá rẹ̀.

4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;

ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore

ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;

àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.