Ní Ìyàsímímọ́ Tẹmpili Solomoni

1004 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 135–136

1 Ẹ yin Olúwa.

Ẹ yin orúkọ Olúwa;

ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.

2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,

nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.

3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;

ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.

4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;

àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.

5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,

àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.

6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,

ní ọ̀run àti ní ayé,

ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.

7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:

ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:

ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.

8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,

àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.

9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,

sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.

10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,

tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.

11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,

ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:

12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.

13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;

ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.

14  Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,

yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,

iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.

16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;

wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;

bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn.

18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:

gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,

ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.

20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;

ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.

21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,

tí ń gbé Jerusalẹmu.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

136:1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

6  Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

7  Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

10  Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

11  Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

13  Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

20 Àti Ogu, ọba Baṣani;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.