Àwọn Sáàmù Dafidi, Tí A Kò Mọ Ọjọ́ Wọn

Àwọn sáàmù tí Dafidi kọ, tí a kò mọ ọjọ́ tí ó kọ wọ́n àti àwọn ipò tí ó wà nígbà tí ó kọ wọ́n.

1015 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 40–41

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

1 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;

ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

2 Ó fà mí yọ gòkè

láti inú ihò ìparun,

láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,

ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,

ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.

3 Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,

àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.

Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,

wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì

tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn

tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,

tàbí àwọn tí ó yapa

lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

5 Olúwa Ọlọ́run mi,

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.

Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;

ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ,

tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,

wọ́n ju ohun tí

ènìyàn le è kà lọ.

6  Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,

ìwọ ti ṣí mi ní etí.

Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀

ni ìwọ kò béèrè.

7 Nígbà náà ni mo wí pé,

“Èmi nìyí;

nínú ìwé kíká ni

a kọ ọ nípa tèmi wí pé.

8 Mo ní inú dídùn

láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,

ìwọ Ọlọ́run mi,

òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

9 Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà

láàrín àwùjọ ńlá;

wò ó,

èmi kò pa ètè mi mọ́,

gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,

ìwọ Olúwa.

10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;

èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.

Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́

kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa;

jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ

kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.

12 Nítorí pé àìníye ibi

ni ó yí mi káàkiri,

ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,

títí tí èmi kò fi ríran mọ́;

wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,

àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13  Jẹ́ kí ó wù ọ́,

ìwọ Olúwa,

láti gbà mí là;

Olúwa,

yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì

kí wọn kí ó sì dààmú;

àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun

jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n,

àwọn tí ń wá ìpalára mi.

15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”

ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.

16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ

kí ó máa yọ̀

kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;

kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ

kí o máa wí nígbà gbogbo pé,

“Gbígbéga ni Olúwa!”

17 Bí ó ṣe ti èmi ni,

tálákà àti aláìní ni èmi,

ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi

àti ìgbàlà mi;

má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,

ìwọ Ọlọ́run mi.

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

41:1 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:

Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.

2 Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:

yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀

kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.

3 Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀

yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

4 Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;

wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.

5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,

“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”

6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,

wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;

nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;

èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,

8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin

àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,

kì yóò dìde mọ́.”

9  Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,

ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,

tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;

gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,

nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

12 Bí ó ṣe tèmi ni

ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi

ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,

láé àti láéláé.

Àmín àti Àmín.

Saamu 61

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

1 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;

tẹ́tí sí àdúrà mi.

2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,

mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;

mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,

ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé

kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.

5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;

Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,

ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.

7 Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;

pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé

kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.