Àwọn Sáàmù Dafidi, Tí A Kò Mọ Ọjọ́ Wọn (continued)

Àwọn sáàmù tí Dafidi kọ, tí a kò mọ ọjọ́ tí ó kọ wọ́n àti àwọn ipò tí ó wà nígbà tí ó kọ wọ́n.

1015 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 65

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.

1 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;

sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,

gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.

3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!

Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.

4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn

tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!

A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,

ti tẹmpili mímọ́ rẹ.

5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,

Ọlọ́run olùgbàlà wa,

ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé

àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,

6 ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,

tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,

7 ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́,

ríru ariwo omi wọn,

àti ìdágìrì àwọn ènìyàn.

8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,

nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;

ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,

ìwọ pè fún orin ayọ̀.

9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;

ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.

Odò Ọlọ́run kún fún omi

láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,

nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.

10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀

ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;

ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,

o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.

11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,

ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.

12 Pápá tútù ní aginjù ń kan

àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.

13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;

àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,

wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.

Saamu 69

Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.

1 Gbà mí, Ọlọ́run,

nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

2 Mo ń rì nínú irà jíjìn,

níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.

Mo ti wá sínú omi jíjìn;

ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;

ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,

nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

4  Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí

wọ́n ju irun orí mi lọ,

púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,

àwọn tí ń wá láti pa mí run.

A fi ipá mú mi

láti san ohun tí èmi kò jí.

5 Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;

ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

6 Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,

Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun;

má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,

Ọlọ́run Israẹli.

7 Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,

ìtìjú sì bo ojú mi.

8 Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;

àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

9  nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,

àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

10 Nígbà tí mo sọkún

tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà

èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

11 nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,

àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.

12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,

mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni

ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,

ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà

Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,

dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.

14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,

má ṣe jẹ́ kí n rì;

gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,

kúrò nínú ibú omi.

15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì

kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.

16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;

nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.

17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:

yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;

rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.

19 Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;

gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.

20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́,

wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́;

mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,

mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,

àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.

22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn

ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ

fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23 Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,

kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.

24  Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn;

kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25  Kí ibùjókòó wọn di ahoro;

kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26 Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,

àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.

27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;

Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.

28  Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè

kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.

29 Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí,

Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.

30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga

èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

31 Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ

ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.

32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:

ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

33 Olúwa, gbọ́ ti aláìní,

kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,

òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,

35 nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là

yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.

Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;

36 àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,

àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.