Peteru kọ̀wé sí àwọn Kristiani Júù àti aláìkọlà
Peteru kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn Júù tí wọ́n, ní àkókò inúnibíni, ti sá di àwọn ilẹ̀ abọ̀rìṣà tí a dárúkọ ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, àti sí àwọn aláìkọlà tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ pẹ̀lú. Ó kọ̀wé láti gbà wọ́n níyànjú láti fi inú dídùn jìyà nítorí ẹ̀sìn wọn, àti láti tẹnumọ́ fún wọn bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa gbé ìgbé ayé mímọ́ àti aláìlábùkù, kí wọ́n lè mú ìtìjú bá ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.
65 tàbí 66 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
Peteru kí àwọn Kristiani Júù àti aláìkọlà
Ìkíni àti ìbùkún Peteru sí àwọn Júù àti aláìkọlà tí a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, tí àwọn wòlíì fihàn, láti di onígbọràn sí ìyìnrere nípa iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Nípa èyí ni wọ́n ní ìpín nínú gbogbo ìbùkún tí ó ń wá láti inú ẹ̀jẹ̀ ètùtù Kristi.
1 Peteru, aposteli Jesu Kristi,
Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia, 2 àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi:
Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.
Peteru Fi Ìbùkún fún Ọlọ́run nítorí Ìbí Wọn Tuntun
Peteru fi ìbùkún fún Ọlọ́run nítorí àtúnbí nípa ẹ̀mí tí ó fi fún àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà tí kì í ṣe Júù, sí ìrètí ìyè lẹ́yìn ikú nípasẹ̀ àjíǹde Jesu Kristi, kí wọ́n lè pín nínú ogún tí kò lè bàjẹ́. Nínú ìrètí ìgbàlà yìí, ó yẹ kí wọ́n máa yọ̀ gidigidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ìpọ́njú ń mú wọn ní ìbànújẹ́. Àwọn ìpọ́njú wọ̀nyí ṣe pàtàkì láti fi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wọn hàn; ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn sì níye lórí ju ti wúrà lọ, nítorí ó ń mú ògo àti ìyìn ayérayé wá fún wọn nígbà wíwá Jesu Kristi. Bí wọn kò tilẹ̀ rí i, wọ́n ń yọ̀ gidigidi nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà, nítorí wọ́n mọ̀ pé wọn yóò gba èrè ìgbàgbọ́ wọn lọ́wọ́ rẹ̀, èyí tí í ṣe ìgbàlà ọkàn wọn. Àwọn wòlíì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbàlà yìí, wọ́n sì fi ìṣọ́ra ṣèwádìí láti mọ àkókò àti àwọn ènìyàn tí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń tọ́ka sí nígbà tí ó jẹ́rìí ṣáájú nípa ìjìyà Kristi àti àwọn ògo àti ìbùkún tí yóò tẹ̀ lé e. Ẹ̀mí Mímọ́ tún fi hàn àwọn wòlíì pé kì í ṣe ara wọn ni wọ́n ń sìn, bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí yóò wà ní àkókò tí ń bọ̀, nípa àwọn nǹkan tí àwọn aposteli ti kéde sí ayé nísinsin yìí; Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà sì fún àwọn aposteli ní agbára fún ète yẹn. Àwọn áńgẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn pẹ̀lú, “ń hára gàgà láti yẹ” àwọn ohun ìjìnlẹ̀ wọ̀nyí “wò” (Eksodu 25:20).
3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5 ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6 Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́. 7 Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9 ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.
10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. 11 Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. 12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.
Ẹ Máa Gbé nínú Ìbẹ̀rù Mímọ́, Ẹ̀jẹ̀ Kristi ti Rà Yín Padà
Láti inú àwọn ìbùkún tí ìjìyà Kristi mú wá, Peteru rọ̀ wọ́n láti ní ìgboyà nínú gbogbo àdánwò wọn, kí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tí a ṣèlérí fún wọn ní ọjọ́ tí a ó fi Kristi hàn máa gbé wọn ró títí dé òpin ayé wọn. Wọ́n gbọdọ̀ yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń tẹ̀lé kí wọ́n tó yí padà, kí wọ́n sì fara wé ìwà mímọ́ Ọlọ́run, ẹni tí ó pè wọ́n láti jẹ́ ọmọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti kọ̀wé (Lefitiku 19:2; 1 Peteru 5:10; 2:21; 3:9). Níwọ̀n bí a ó ti ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, láìsí ojúsàájú, a rọ̀ wọ́n láti lo àkókò àtìpó wọn lórí ilẹ̀ ayé nínú ìbẹ̀rù ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ó tún yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí a ti rà wọ́n padà kúrò nínú àwọn ìgbàgbọ́ asán, àṣà tàbí ètò ìjọ́sìn ìbàjẹ́ tí wọ́n jogún lọ́wọ́ àwọn baba wọn, nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi, bí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní àbàwọ́n. A ti yan Kristi nínú ète Ọlọ́run ṣáájú ìpìlẹ̀ ayé, àwọn ẹbọ tí Òfin là sílẹ̀ sì jẹ́ àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣáájú, ṣùgbọ́n a fi í hàn ní sáà ìkẹyìn, èyí tí í ṣe sáà ìhìnrere, fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú láti mọ̀ ọ́n. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú àánú Ọlọ́run tí a fihàn nínú ẹbọ Kristi yìí, wọ́n gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì gbé e ga sí ògo ọ̀run, kí ìgbàgbọ́ wọn lè fìdí múlẹ̀ nínú ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run, kí ìrètí wọn fún ògo àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi sì lè wà nínú Ọlọ́run.
13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 16 Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”
17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín. 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
A ti Tún Yín Bí, Ẹ Fẹ́ràn Ara Yín
Peteru rọ àwọn tí ọkàn wọn ti di mímọ́ kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara nípa gbígbà Kristi Jesu gbọ́ láti fẹ́ràn ara wọn, kì í ṣe pẹ̀lú ìhùwàsí àti ọ̀rọ̀ àgàbàgebè, bí kò ṣe pẹ̀lú ọkàn mímọ́ tí ó bọ́ lọ́wọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin tí a tún bí. A tún wọn bí, kì í ṣe nípa ìran àwọn òbí ènìyàn, bí kò ṣe láti orísun ti Ọlọ́run àti ti ọ̀run, èyí ni ẹ̀kọ́ Ọlọ́run alààyè, tí ó dúró títí láé.
22 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23 Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 24 Nítorí pé,
“Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,
àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.
Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,
25 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”
Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín.
Àwọn Òkúta Alààyè nínú Tẹmpili Ẹ̀mí Ọlọ́run
Peteru rọ̀ wọ́n láti fi gbogbo ìtẹ̀sí búburú ti ìwà wọn àtijọ́ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa yán hànhàn fún wàrà mímọ́ ti ìhìnrere gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ọwọ́ tí a tún bí nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, kí ìwà wọn tuntun lè rí oúnjẹ gbà kí ó sì dàgbà dé ìpé, níwọ̀n bí wọ́n ti tọ́ oore àti dídára Olúwa wò tẹ́lẹ̀ nínú ìbí wọn kejì, èyí tí í ṣe ti ẹ̀mí (Sáàmù 34:8). Bí wọ́n ṣe ń tọ̀ ọ́ wá nípa ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí òkúta ìpìlẹ̀ alààyè, a ń kọ́ wọn lé e lórí, wọ́n sì ń pín nínú ìyè rẹ̀, láti di tẹmpili ti ẹ̀mí àti ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà (Eksodu 19:6; Ìfihàn 1:6), tí a yàn láti máa rú ẹbọ àdúrà àti ìyìn nípasẹ̀ Kristi. Bákan náà ni Isaiah kéde (Isaiah 28:16) pé a ó fi “òkúta igun ilé tí a yàn, tí ó sì ṣeyebíye” lélẹ̀ ní Sioni gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ tẹmpili tuntun Ọlọ́run, tí yóò so ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ilé náà, àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà, pọ̀ di ìjọ kan (ará Efesu 2:21). Àwọn tí ó gbàgbọ́ jẹ́ apá kan ilé yìí. Ṣùgbọ́n nípa àwọn aláìgbọràn, a kọ ọ́ pé (Sáàmù 118:22) òkúta ìpìlẹ̀ tí a kọ̀ sílẹ̀ yìí “ti di òkúta igun ilé” tẹmpili tuntun Ọlọ́run, àti “òkúta ìkọ̀sẹ̀” fún àwọn tí kò gba Kristi gbọ́, èyí tí wọn yóò kọsẹ̀ lé, tí wọn yóò sì ṣubú, tí wọn yóò sì fọ́ sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Isaiah ti sọ tẹ́lẹ̀ (Isaiah 8:14–15). Peteru ṣàpèjúwe àwọn àǹfààní gíga tí àwọn Kristiani ní pẹ̀lú àwọn orúkọ oyè tí a ti fi fún ìjọ Júù nígbà kan rí, fún gbogbo àwọn tí a mú wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run.
1 Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo. 2 Bí ọmọ ọwọ́ tuntun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yin lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà, 3 nísinsin yìí tí ẹ̀yin ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa.
4 Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. 5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. 6 Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:
“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
ojú kì yóò tì í.”
7 Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,
“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”
8 àti pẹ̀lú,
“Òkúta ìdìgbòlù,
àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”
Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
9 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn. 10 Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.
Gẹ́gẹ́ bí Àjèjì, Ẹ Tẹríba fún Gbogbo Ìjọba Ènìyàn
Ní títọ́ka sí àwọn ọmọ Israẹli ìgbàanì (ará Heberu 11:13), Peteru rọ̀ wọ́n, gẹ́gẹ́ bí àjèjì àti arìnrìn-àjò, èyí tí wọ́n jẹ́ ní tòótọ́ ní Asia, Pọntu àti àwọn ilẹ̀ mìíràn, tí wọn kò ní ogún lórí ilẹ̀ ayé, láti máa wá orílẹ̀-èdè ti ọ̀run àti láti yẹra fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, tí ń sọ ọkàn di ẹrú tàbí pa á run. Kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé tí iṣẹ́ rere wọn yóò fi lè tako ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. Kí wọ́n tẹríba fún gbogbo irú ìjọba ènìyàn nítorí Olúwa, kí wọ́n lè pa ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan àwọn aṣiwèrè lẹ́nu mọ́, àwọn tí wọ́n sọ pé ẹ̀sìn wọn mú kí wọn má fẹ́ wà lábẹ́ àṣẹ àwọn ọba àti onídàájọ́. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí Ọlọ́run yàn, àwọn Júù ṣògo pé àwọn jẹ́ òmìnira, tí òfin tiwọn ń darí. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, Peteru rọ̀ wọ́n láti jẹ́ kí òfin ẹ̀sìn wọn máa darí wọn nínú ọkàn, ṣùgbọ́n kí wọn má ṣe fi òmìnira wọn bo ìṣọ̀tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí àwọn Júù ti ṣe, bí kò ṣe kí wọ́n máa gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
11 Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àjèjì àti àtìpó, láti fàsẹ́yìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun. 12 Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.
13 Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa, ìbá à ṣe fún ọba tàbí fún olórí. 14 Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere. 15 Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn. 16 Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run. 17 Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ́ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba.
Kí Àwọn Ìránṣẹ́ Fara Da Ìjìyà bí Kristi ti Jìyà
Peteru rọ àwọn ẹrú ilé àti àwọn ìránṣẹ́ láti gbọ́ràn sí àwọn ọ̀gá wọn pẹ̀lú ìtẹríba àti ọ̀wọ̀, àní àwọn oníkà àti aláìṣòdodo pàápàá, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ìwà àwọn tí wọ́n ń sìn pinnu ìgbọràn wọn. Kí wọ́n fara da ìjìyà nítorí ṣíṣe rere, ní títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, ẹni tí ó jìyà fún wọn kí wọ́n lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú rẹ̀ (Isaiah 53:6). Ó ru ìjìyà tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè gba ènìyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ agbára rẹ̀.
18 Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú. 19 Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run. 20 Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 21 Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀:
22 “Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan,
bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.”
23 Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́. 24 Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo, nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá. 25 Nítorí tí ẹ̀yin ń ṣáko lọ bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ti padà sí ọ̀dọ̀ olùṣọ́-àgùntàn àti bíṣọ́ọ̀bù ọkàn yín.