Paulu Kọ̀wé sí Àwọn ará Kọrinti

Paulu kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọrinti láti fìdí àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aposteli múlẹ̀, láti bá ìjọ wí nítorí àwọn ìwà àìtọ́ àti rúdurùdu inú rẹ̀, àti láti dáhùn àwọn ìbéèrè àwọn tí ó yí padà sí ìgbàgbọ́ lórí onírúurú kókó ẹ̀kọ́ àti ìbáwí.

57 lẹ́yìn ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Paulu Kí Àwọn ará Kọrinti

Ọ̀rọ̀ ìṣáájú Paulu, nínú èyí tí ó ti fìdí ipò aposteli rẹ̀ àti ìṣọ̀kan àwọn tí ó gba Kristi Jesu gbọ́ múlẹ̀.

1 Kọrinti 1:1–3

1  Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa,

2  Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà:

3  Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

Paulu Yọ̀ sí Ìyípadà Wọn sí Ìgbàgbọ́ àti Àwọn Ẹ̀bùn Wọn

Paulu yọ̀ sí ìyípadà wọn sí ìgbàgbọ́ àti sí àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí òtítọ́ Kristi.

1 Kọrinti 1:4–9

4  Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. 5 Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. 6 Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. 7 Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. 8  Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi. 9  Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

Paulu Rọ Wọ́n sí Ìṣọ̀kan, Kì í Ṣe sí Ìpínyà

Paulu rọ̀ wọ́n láti wà ní ìṣọ̀kan ní orúkọ Jesu Kristi, ẹni tí kò sí ìpínyà nínú rẹ̀, dípò kí wọ́n máa tẹ̀lé àwọn aṣáájú tí wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ lábẹ́ orúkọ wọn.

1 Kọrinti 1:10–17

10 Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà. 11 Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín. 12  Ohun tí mo ń sọ ní pé, olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo”; òmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

13  Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí? 14  Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiusi. 15 Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi. 16  (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi). 17  Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìyìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.

Àgbélébùú Ju Ọgbọ́n Ènìyàn Lọ

Paulu tẹnu mọ́ ọn pé a rán òun láti wàásù ìhìnrere, kì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ó fi ìmọ̀ àti òye hàn, kí a má baà gbójú fo agbára Ọlọ́run. Ó kéde pé a kò lè fi ọgbọ́n tàbí ẹ̀kọ́ ènìyàn ṣàwárí àwọn òtítọ́ ìhìnrere. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwàásù àgbélébùú dàbí òmùgọ̀ lójú àwọn tí kò gbàgbọ́, ó ju ọgbọ́n ènìyàn lọ, ó sì jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà àwọn Júù àti Giriki tí ó yí padà sí ìgbàgbọ́. Ọlọ́run ti yan àwọn ènìyàn tí a kẹ́gàn jù lọ láti fi àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tí ó kẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn ńlá láàárín àwọn Júù sí ìtìjú, àwọn tí wọ́n gbé ara wọn dìde sí ọgbọ́n ìhìnrere. Nípa fífi wọ́n wéra, ó fi hàn bí gbogbo àṣeyọrí ènìyàn ti kéré tó, kí ẹnikẹ́ni má baà ṣògo bí kò ṣe nínú Olúwa.

1 Kọrinti 1:18–31

18 Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. 19  Nítorí a tí kọ ọ́ pé:

“Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,

òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

20 Àwọn ọlọ́gbọ́n náà ha dá? Àwọn akọ̀wé náà ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di aṣiwèrè? 21 Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́. 22  Nítorí pé àwọn Júù ń béèrè àmì, àwọn Helleni sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n, 23  ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí. 24 Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run. 25 Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.

26 Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i. 27  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára. 28  Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán. 29  Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀. 30  Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa. 31  Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

Paulu Wàásù Láìlo Ọgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ènìyàn

Paulu kéde pé nígbà tí òun wàásù ìhìnrere fún wọn, òun kò ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tàbí ọgbọ́n ọ̀rọ̀ ènìyàn, bí àwọn olùkọ́ èké wọn ti ṣe. Àwọn àríyànjiyàn rẹ̀ wá láti inú ẹ̀rí ìṣípayá Ọlọ́run, tí agbára iṣẹ́ ìyanu sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Nítorí náà, ìgbàgbọ́ wọn kò yẹ kí ó sinmi lé ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ ọgbọ́n orí ènìyàn.

1 Kọrinti 2:1–5

1  Nígbà tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. 2  Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 3  Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. 4  Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. 5  Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

Ọgbọ́n Ọlọ́run tí Ó Farasin Di Mímọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí

Lẹ́yìn náà, Paulu fi hàn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò lo ọgbọ́n ayé, àwọn ará Kọrinti kò ní ìdí láti ṣògo nípa àwọn olùkọ́ èké wọn. Nítorí ó ń sọ àṣírí Ọlọ́run tí ó farasin, tí Ẹ̀mí ti ṣí payá fún un, èyí tí kò sí ìsapá tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ ènìyàn tí ó lè dé ibẹ̀. Nípasẹ̀ ìwàásù Ẹ̀mí Mímọ́, ó ń kéde àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún wọn, èyí tí Ẹ̀mí Ọlọ́run nìkan lè ṣí payá. Àní ènìyàn àdánidá tí kì í ṣe ti ẹ̀mí, tí kò ní ìrànlọ́wọ́ mìíràn ju agbára ènìyàn rẹ̀ lọ, kò lè gbà wọ́n.

1 Kọrinti 2:6–16

6  Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán. 7  Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 8  Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 9  Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ojú kò tí ì rí,

etí kò tí í gbọ́,

kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀

ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ ẹ.”

10  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. 11 Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnra rẹ̀. 12  Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 13  Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14  Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

16  “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,

ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.