Ìpínyà Nítorí Àwọn Òjíṣẹ́ Ń Pa Ìgbésí Ayé Ẹ̀mí Run

Paulu fi hàn pé ìyapa nínú ìjọ, tí ó ń wá láti inú èrò àwọn ènìyàn nípa onírúurú ẹ̀bùn àwọn ìránṣẹ́ wọn, ń pa ìgbésí ayé ẹ̀mí run.

57 lẹ́yìn ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Kọrinti 3:1–10

1  Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, àní bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Kristi. 2  Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ; nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a. 3 Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà ṣe wà láàrín ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí? 4  Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”

5  Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù. 6  Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. 7 Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. 8 Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. 9  A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.

10  Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e.

Kristi Ni Ìpìlẹ̀ Kan Ṣoṣo

Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo ti ẹ̀sìn Kristiani. A kìlọ̀ fún àwọn tí ń kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ yìí láti ṣọ́ra, nítorí wọ́n gbọ́dọ̀ la ìdánwò líle kọjá. Olùkọ́ tí ó ti mú ẹ̀kọ́ èké wọlé yóò rí àwọn tí ó yí padà sí ìgbàgbọ́ ṣubú kúrò ní àkókò inúnibíni, bí igi, koríko gbígbẹ àti pòròpórò nínú iná, òun fúnra rẹ̀ yóò sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìṣòro. Ní òdì kejì, àwọn tí wọ́n ti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro tí ó sì dára sórí ìpìlẹ̀ yìí yóò rí àwọn tí wọ́n yí padà sí ìgbàgbọ́ la ìdánwò iná kọjá bí fàdákà àti wúrà, olùkọ́ náà fúnra rẹ̀ yóò sì gba èrè iṣẹ́ rẹ̀.

1 Kọrinti 3:11–15

11  Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. 12 Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 13  Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14 Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. 15  Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.

Ọgbọ́n Ayé Yìí Jẹ́ Òmùgọ̀

Paulu sọ pé olùkọ́ tí ó mọ̀ọ́mọ̀ mú ẹ̀kọ́ èké wọ ìjọ yóò parun, bí ó ti wù kí ó ṣe àṣeyọrí tó. Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ ní ojú Ọlọ́run. Nítorí náà, wọn kò gbọdọ̀ máa ṣògo nínú àwọn olùkọ́ wọn tàbí nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n ń gbé lárugẹ, kí wọ́n má bàa dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. Ògo tòótọ́ ti Kristiani wà nínú Kristi, ẹni tí í ṣe ti Ọlọ́run, àti ẹni kan ṣoṣo tí a tipasẹ̀ rẹ̀ gba àwọn ìlérí ìgbàlà, èyí tí àwọn oníwàásù ìhìnrere kò lè fi fúnni.

1 Kọrinti 3:16–23

16  Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? 17 Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹmpili Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹmpili Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yin jẹ́.

18  Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. 19  Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; 20  lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” 21  Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo. 22  Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn. 23 Ẹ̀yin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọ́run.

Ọlọ́run Nìkan Ni Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀

A béèrè lọ́wọ́ àwọn aposteli, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Kristi, láti máa sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere fún àwọn ènìyàn bí wọ́n ṣe múra tán láti gbà wọ́n. Ní ìdáhùn sí àríwísí àwọn olùkọ́ èké pé kò kọ́ àwọn ará Kọrinti ní àwọn ẹ̀kọ́ jíjinlẹ̀ ti ẹ̀sìn Kristiani, Paulu sọ pé kí ìdájọ́ ènìyàn dá òun lẹ́bi kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, nítorí Ọlọ́run nìkan ni ó lè ṣe ìdájọ́ òdodo, òun nìkan sì ni ó mọ àṣírí ọkàn. Nítorí náà, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe dá àwọn olùkọ́ wọn nípa tẹ̀mí lẹ́jọ́.

1 Kọrinti 4:1–5

1  Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọ̀fẹ́ láti mọ Kristi tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. 2 Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú, ni kí ó jẹ́ olóòtítọ́. 3 Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́. 4  Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi. 5  Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

A Kẹ́gàn Àwọn Aposteli, A Bọlá Fún Àwọn Olùkọ́ Èké

Paulu sọ pé òun ti lo orúkọ ara òun àti ti Apollo kí wọ́n lè kọ́ láti má ṣe gbé àwọn olórí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọn ga jù, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ má ṣe kún fún ìgbéraga, ìbínú àti ẹ̀gàn sí ara wọn. Ìránṣẹ́ Kristi lásán ni Paulu àti Apollo, nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn sì ni àwọn Kristiani ti gbàgbọ́. Wọ́n kọ gbogbo oyè àti ipò àrà ọ̀tọ̀ láàárín wọn, kí àwọn ará Kọrinti lè tipasẹ̀ àpẹẹrẹ wọn kọ́ láti má ṣe gbé àwọn olùkọ́ wọn ga ju ohun tí Paulu ti kọ lọ. Lẹ́yìn náà, Paulu yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùkọ́ èké. A ń pe àwọn aposteli ní aláìmọ̀kan àti òmùgọ̀ nítorí pé wọ́n ń wàásù kókó àkọ́kọ́ nínú ìgbàgbọ́ Kristiani, nígbà tí a ka àwọn olùkọ́ èké sí ọlọ́gbọ́n àti onímọ̀ ọgbọ́n orí nítorí àwọn àròjinlẹ̀ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. A ń kẹ́gàn àwọn aposteli; a sì ń bu ọlá fún àwọn olùkọ́ èké. Àwọn aposteli dojú kọ gbogbo irú ewu, nígbà tí àwọn olùkọ́ èké ń gbádùn ọrọ̀ àti gbogbo ìrọ̀rùn.

1 Kọrinti 4:6–13

6  Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” 7 Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

8 Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! 9  Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10  Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11  Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. 12  Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. 13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.

Paulu Kìlọ̀ Fún Wọn Gẹ́gẹ́ Bí Baba Wọn

Paulu sọ pé òun kò kọ àwọn nǹkan wọ̀nyí láti dójútì wọ́n, bí kò ṣe láti kọ́ wọn àti láti kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn olùkọ́ èké, tí kò ní jẹ́ ohun tí òun jẹ́ fún wọn, baba wọn nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, ó rọ̀ wọ́n láti fara wé òun, ó sì rán Timotiu sí wọn láti rán wọn létí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

1 Kọrinti 4:14–17

14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́. 15  Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìnrere. 16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi. 17  Nítorí náà ni mo ṣe rán Timotiu sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.

Paulu Yóò Wá, Láti Fi Ìyà Jẹ Wọ́n Tàbí Nínú Ìfẹ́

Olùkọ́ èké náà ti sọ pé ẹ̀rù ń ba Paulu láti dojú kọ àwọn alátakò tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ tí wọ́n sì mọ ọ̀rọ̀ sọ báyìí. Paulu sọ pé òun pinnu láti bẹ̀ wọ́n wò láìpẹ́, nígbà tí yóò ṣàyẹ̀wò, kì í ṣe ọ̀rọ̀ àwọn alátakò rẹ̀, bí kò ṣe agbára wọn tí ó kọjá ti ẹ̀dá, nítorí pé a fi ìdí ìhìnrere múlẹ̀, kì í ṣe nípasẹ̀ ọgbọ́n tí àwọn oníwàásù rẹ̀ ń gbé lárugẹ, bí kò ṣe nípasẹ̀ agbára iṣẹ́ ìyanu tí a fi fún wọn láti jẹ́rìí sí i. Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá kí òun lo agbára òun tí ó kọjá ti ẹ̀dá láti fi ìyà jẹ wọ́n, tàbí kí òun wá sí wọn ní ẹ̀mí àlàáfíà àti ìfẹ́ nítorí wọ́n ti ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe wọn.

1 Kọrinti 4:18–21

18 Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbèéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà mi láti wá sọ́dọ̀ yín. 19 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí ṣe ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní. 20 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára. 21  Èwo ni ẹ yàn? Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàṣán, tàbí ni ìfẹ́, àti ẹ̀mí tútù?