Paulu Fún Àwọn Ọkùnrin àti Obìnrin ní Ìtọ́ni nípa Ìjọsìn

A tún tẹnumọ́ ojúṣe àdúrà. A pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin láti gbadura ní gbangba, àdúrà tí kò yẹ kí a fi mọ́ sí sínágọ́gù tàbí tẹmpili ní Jerusalẹmu nìkan; bí a bá gbadura pẹ̀lú ìfọkànsìn, àdúrà náà jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní gbogbo ibi. A rọ àwọn obìnrin Kristiani láti máa ṣe iṣẹ́ rere àti láti dákẹ́. Aṣọ wọn gbọ́dọ̀ bá ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ mímọ́ wọn mu. Nítorí ìrékọjá obìnrin, ó gbọ́dọ̀ wà lábẹ́ ọkùnrin. Ègún tí a fi lé e lórí yóò dín kù bí ó bá ní ìgbàgbọ́ àti ìwà mímọ́.

57 lẹ́yìn ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Timotiu 2:8–15

8 Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn. 9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, 10 bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.

11 Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́. 12 Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́. 13  Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa. 14  Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀. 15 Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.

Àwọn Ànímọ́ Bíṣọ́ọ̀pù àti Ìránṣẹ́

A ṣàpèjúwe àwọn ànímọ́ bíṣọ́ọ̀pù, ẹni tí ó ń bójú tó ọ̀pọ̀ ìjọ, àti ti ìránṣẹ́ tí ó ń bójú tó ìjọ kan.

1 Timotiu 3:1–7

1 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò alábojútó, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́. 2 Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. 3 Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó. 4 Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo. 5 Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run? 6 Kí ó má jẹ́ ẹni tuntun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má ba à gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi èṣù. 7 Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má ba à bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ̀kùn èṣù.

Bí Àwọn Díákónì àti Àwọn Ìyàwó Wọn Gbọdọ̀ Jẹ́

A tò àwọn ànímọ́ àwọn díákónì sílẹ̀. Àwọn ìyàwó wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ènìyàn.

1 Timotiu 3:8–13

8 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò. 9 Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun. 10 Kí a kọ́kọ́ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn.

11 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo.

12 Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára. 13 Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

Paulu Gba Timotiu Níyànjú Nínú Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀

Paulu gba Timotiu níyànjú nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí bíṣọ́ọ̀pù àti ìránṣẹ́ nípa rírán an létí àwọn ẹ̀kọ́ tí ó túbọ̀ ga ti ẹ̀sìn Kristiani.

1 Timotiu 3:14–16

14 Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. 15 Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. 16 Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run:

ẹni tí a fihàn nínú ara,

tí a dá láre nínú Ẹ̀mí,

ti àwọn angẹli rí,

tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

tí a gbàgbọ́ nínú ayé,

tí a sì gbà sókè sínú ògo.

Paulu Sọ Ìpẹ̀yìndà Ìjọ Tẹ́lẹ̀

Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run, Paulu sọ ìpẹ̀yìndà ìjọ Kristiani tẹ́lẹ̀, ó sì ṣàpèjúwe irú ìbàjẹ́ rẹ̀, ó ń tọ́ka sí i pé àwọn olùkọ́ tí ń fẹ́ kí a tẹ̀ lé àṣà àwọn Júù wà lára àwọn tí ń pèsè ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀. A kìlọ̀ fún Timotiu láti yẹra fún gbogbo ìtẹ̀sí sí àwọn ìbàjẹ́ wọ̀nyí, a sì rọ̀ ọ́ láti kọ́ni pé ṣíṣe rere àti ìwà-bí-Ọlọ́run nìkan ni iṣẹ́ Kristiani tí ó ní èrè tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà. A sọ fún un láti tẹnu mọ́ òtítọ́ pàtàkì yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ó kẹ́gàn rẹ̀, a ó sì ṣe inúnibíni sí i nítorí èyí.

1 Timotiu 4:1–11

1 Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. 2 Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. 3 Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. 4 Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. 5 Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.

6 Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé. 7 Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. 8 Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. 9 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. 10 Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.

11 Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni.

Paulu Tọ́ Timotiu Sí Ọ̀nà Nípa Ìwà Rẹ̀ Fúnra Rẹ̀

Paulu fún Timotiu ní ìtọ́nisọ́nà nípa ìwà rẹ̀ fúnra rẹ̀, ó sì fẹ́ kí ó fi gbogbo kókó ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀ sílẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ di àpẹẹrẹ fún ìjọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́, kíkà, kíkẹ́kọ̀ọ́, àṣàrò, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, yóò gba ara rẹ̀ là, yóò sì jẹ́ ọ̀nà ìgbàlà fún àwọn ẹlòmíràn.

1 Timotiu 4:12–16

12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́. 13 Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni. 14 Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

15 Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. 16 Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.