A Dá Abrahamu Láre Kí Ó Tó Kọlà
Paulu fi hàn pé kì í ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ òfin ni a dá Abrahamu láre. Kò ní ohun kan láti ṣògo lé lórí. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni a dá a láre, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ojúrere, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí gbèsè, tàbí èrè tí ó tọ́ sí i nítorí iṣẹ́ rẹ̀. Dafidi jẹ́rìí sí ọ̀nà ìdáláre kan náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú òtítọ́ pé a dá Abrahamu láre nígbà tí kò tí ì kọlà, àti pé lẹ́yìn náà ni ó gba àmì ìkọlà gẹ́gẹ́ bí èdìdì ìdáláre rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, kí ó lè di baba nípa ti ẹ̀mí fún àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà, tí àwọn méjèèjì yóò ní ẹ̀tọ́ sí ìdáláre bákan náà lórí ipò kan ṣoṣo, èyí ni ìgbàgbọ́ nìkan.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. 2 Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. 3 Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”
4 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore-ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. 5 Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo. 6 Gẹ́gẹ́ bí Dafidi pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́.
7 Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn
ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
8 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.”
9 Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. 10 Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. 11 Ó sì gbé àmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. 12 Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.
Ìlérí fún Abrahamu Kan Àwọn Aláìkọlà Pẹ̀lú
Paulu tẹ̀ síwájú nínú àríyànjiyàn rẹ̀ nípa sísọ fún àwọn Júù pé ìlérí tí a ṣe fún Abrahamu fúnra rẹ̀ fi hàn pé gbogbo ayé yóò di ajogún rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí àwọn Júù nìkan bá ni yóò jẹ́ ajogún ìlérí rẹ̀, a sọ ìgbàgbọ́ di asán, a sì fagi lé ìlérí tí a ṣe lórí ipò ìgbàgbọ́. Nítorí òfin, láìsí àánú, fi ẹlẹ́ṣẹ̀ sábẹ́ ìjìyà, láìsí òfin kò sì lè sí ìlànà nípa ohun tí ó yẹ kí ènìyàn ṣe, nítorí náà kò lè sí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí èyí ni a ṣe fúnni ní ìlérí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fúnni lọ́fẹ̀ẹ́ sì kan àwọn ọmọ Abrahamu nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí. Ìdáláre Abrahamu nígbà tí kò tí ì kọlà fi hàn pé a tẹ́wọ́ gba àwọn aláìkọlà. Ìlérí náà fúnra rẹ̀, tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìkọlà sí gbogbo ìbùkún ìràpadà múlẹ̀.
13 Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́. 14 Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára. 15 Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú, ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀.
16 Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá, 17 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.
18 Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” 19 Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara. 20 Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run, 21 pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. 22 Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un.
A Ṣe Àkọsílẹ̀ Ìgbàgbọ́ Abrahamu Nítorí Wa
A ṣe àkọsílẹ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba Abrahamu nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nítorí wa. Ó fi hàn wá pé ọ̀nà kan ṣoṣo sí ìgbàlà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí ó sì jíǹde gẹ́gẹ́ bí ìdánilójú ìlàjà wa, tàbí ìdáláre wa.
23 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. 24 Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. 25 Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.
Àwọn Ìbùkún Tí Ó Tẹ̀ Lé Ìdáláre
Paulu tẹ̀síwájú láti ṣe àkójọ àwọn ìbùkún àti àǹfààní ńlá tí ó ń tẹ̀lé ìdáláre nípa ìgbàgbọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún àwọn aláìkọlà tí kì í ṣe Júù fi ìfẹ́ Ọlọ́run sí wọn hàn, ikú tí Kristi kú fún wọn nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ abọ̀rìṣà sì fi ìfẹ́ yìí múlẹ̀. Nítorí náà, àwọn aláìkọlà tí kì í ṣe Júù ní ìrètí ìgbàlà kan náà nípasẹ̀ Kristi, wọ́n sì ní ìdí kan náà láti yọ̀ nínú Ọlọ́run bí àwọn ọmọ Abrahamu nípa ẹ̀jẹ̀, nítorí pé a ti mú wọn padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ètùtù kan náà.
1 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 2 Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. 3 Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú, bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; 4 àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí. 5 Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.
6 Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo, ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 8 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
9 Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.
Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Nípasẹ̀ Adamu, Ìyè Nípasẹ̀ Kristi
Paulu wá sọ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àbínibí kalẹ̀. Ó fi hàn pé nípasẹ̀ ìrékọjá ènìyàn kan ni ẹ̀ṣẹ̀ wọ ayé, tí ìdájọ́ ikú sì dé bá gbogbo ènìyàn, nítorí pé gbogbo wọn tí a bí lẹ́yìn náà ni a bí pẹ̀lú ìwà ẹ̀ṣẹ̀. Ikú jọba nípasẹ̀ ìbàjẹ́ ìwà wa kí a tó mọ Òfin Mose. Adamu, ẹni tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀ àti orí ìran ènìyàn ní ti ayé, fi ẹ̀ṣẹ̀ jogún àwọn ènìyàn. Kristi, ẹni tí àpẹẹrẹ náà ń tọ́ka sí àti orí ní ti ẹ̀mí, fi ìyè àti ìdáláre fún gbogbo ènìyàn. Àwọn àbájáde ìgbọràn Kristi tóbi ju àwọn àbájáde àìgbọràn Adamu lọ. Nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kan, Adamu mú ìrékọjá àti ikú wọ ayé. Nípasẹ̀ ìgbọràn rẹ̀, Kristi mú ibi tí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe kúrò, ó sì tipasẹ̀ òdodo ìgbàgbọ́ dá ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ìyè àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn padà fún gbogbo aráyé, fún ẹ̀ṣẹ̀ àbínibí àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn dá fúnra rẹ̀. Òfin wọlé láti jẹ́ kí a mọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn Ọlọ́run pọ̀ yanturu láti gbà wá lọ́wọ́ ìdálẹ́bi Òfin. Bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jọba lórí gbogbo ènìyàn, tí ó fi gbogbo aráyé sábẹ́ ikú ní ti ẹ̀mí àti ní ti ayé, bẹ́ẹ̀ náà ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run yóò jọba, tí yóò mú ìwà mímọ́ jáde, èyí tí ó ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun.
12 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀.
13 Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 14 Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.
15 Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 16 Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà, nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre. 17 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jẹ ọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jẹ ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jesu Kristi.
18 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. 19 Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.
20 Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. 21 Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.