Àwọn Ìkìlọ̀ pé Ìgbèkùn Dájú (continued)

Onírúurú àsọtẹ́lẹ̀ àti ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Júù, tí ń kéde pé ìgbèkùn wọn àti ìparun Jerusalẹmu dájú.

609 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jeremiah 16–17

1 Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.” 3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn. 4 “Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”

5 Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má ṣe lọ síbẹ̀ láti káàánú tàbí ṣọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí. 6 “Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn. 7 Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í ṣọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún baba tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.

8 “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àjọyọ̀ wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu. 9 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.

10 “Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’ 11 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́. 12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Wò ó bí gbogbo yín ṣe ń rìn, olúkúlùkù yín nínú agídí ọkàn búburú rẹ̀, dípò kí ẹ fi gbọ́ tèmi. 13 Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí baba yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn ọlọ́run kéékèèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’

14 “Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ, Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’ 15 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.

16 “Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta. 17 Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18 Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.”

19 Olúwa, alágbára àti okun mi,

ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú,

àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti

òpin ayé wí pé,

“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,

ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.

20 Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run

fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,

ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”

21 “Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn

ní àkókò yìí,

Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú agbára àti títóbi mi.

Nígbà náà ni wọn ó mọ

pé orúkọ mi

ní Olúwa.

17:1 “Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,

èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,

sórí wàláà oókan àyà wọn,

àti sórí ìwo pẹpẹ yín.

2 Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ

àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ

àti àwọn òkè gíga.

3 Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀

àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ

pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó

pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.

4 Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin

yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.

Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú

ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀,

nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi,

èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

5 Báyìí ni Olúwa wí:

“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,

tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,

àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,

kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,

yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,

ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

7  “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin

náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi

Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò

tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò

kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,

gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù

kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá

bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

9 Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,

ó kọjá ohun tí a lè wòsàn.

Ta ni èyí lè yé?

10  “Èmi Olúwa ń wo ọkàn

àti èrò inú ọmọ ènìyàn,

láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,

àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé

ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo.

Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀,

àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀

ní ibi ilé mímọ́ wa.

13 Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;

gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.

Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ

ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,

nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,

orísun omi ìyè sílẹ̀.

14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,

gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,

nítorí ìwọ ni ìyìn mi.

15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:

“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?

Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”

Ni Olúwa wí.

16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,

ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.

Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.

17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,

ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.

18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,

ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,

jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.

Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,

fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

19 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21 Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.” 23 Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí. 24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà. 25 Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé. 26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa. 27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”