A Sun Tẹmpili ní Jerusalẹmu (continued)
588 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,
Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
2 Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;
san ẹ̀san fún agbéraga
ohun tí ó yẹ wọ́n.
3 Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,
Olúwa
tí àwọn ẹni búburú
yóò kọ orin ayọ̀?
4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
kún fún ìṣògo.
5 Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa:
wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
6 Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,
wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.
7 Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;
Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”
8 Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn;
ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?
Ẹni tí ó dá ojú?
Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?
Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11 Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;
ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.
12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí
ìwọ bá wí, Olúwa,
ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,
13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,
títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
14 Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀,
Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,
àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn
dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.
16 Ta ni yóò dìde fún mi
sí àwọn olùṣe búburú?
Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,
èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.
18 Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,
Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,
ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ
ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo
wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,
àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni
tí mo ti ń gba ààbò.
23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn
yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn
Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
17 Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.
18 Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó sì wá láti Libina. 19 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 20 Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.
Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.
4 Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.
2 Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Sedekiah, ni a wó odi ìlú náà.
4 Nígbà tí Sedekiah ọba Juda àti àwọn ọmọ-ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba lọ láàrín ẹnu ibodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.
5 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 6 Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda. 7 Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.
8 Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu. 9 Nebusaradani olórí àwọn ọmọ-ogun mú lọ sí ìgbèkùn Babeli pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú.
3 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 4 Nígbà náà odi ìlú náà sì fọ́nká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun sálọ ní òru láti ẹnu-ọ̀nà bodè láàrín ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, àwọn ará Babeli wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sálọ sí ìkọjá Arabah. 5 Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, 6 wọ́n sì mú un.
Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 7 Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.
8 Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún kọkàndínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu; 9 ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńlá ńlá ni ó dáná sun. 10 Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 11 Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 12 Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko.
13 Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli. 14 Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, àti ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, èyí tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.
16 Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan, àti ìjókòó wọ̀n-ọn-nì tí Solomoni ti ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èló wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ. 17 Gíga ọ̀wọ́n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún, àti ọnà-orí rẹ̀ idẹ ni: àti gíga ọnà-orí náà ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti iṣẹ́ híhun náà, àti àwọn pomegiranate tí ó wà lórí ọnà-orí náà yíká, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́n yìí sì ni ọ̀wọ́n kejì pẹ̀lú iṣẹ́ híhun.
18 Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 19 Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú. 20 Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 21 Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.