Orin Solomoni (continued)

1001 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Orin Solomoni 3–5

1 Ní orí ibùsùn mi ní òru

mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;

mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

2 Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,

ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;

èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.

Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

3 Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi

bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.

“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4 Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀

ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.

Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ

títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,

sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.

5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,

mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú

kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè

kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

6 Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá

bí ọ̀wọ̀n èéfín

tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára

pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?

7 Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,

àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,

àwọn akọni Israẹli,

8 gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,

gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,

idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,

wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

9 Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;

o fi igi Lebanoni ṣe é.

10 Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀,

o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀.

Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,

inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí.

“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

11 Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,

kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,

adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e

ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,

ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Olùfẹ́

4:1 Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!

Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!

Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ

irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.

Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.

2 Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò

tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;

olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;

kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.

3 Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;

ẹnu rẹ̀ dùn.

Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate

lábẹ́ ìbòjú rẹ.

4 Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,

tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;

lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́,

gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

5 Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì

tí wọ́n jẹ́ ìbejì

tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.

6 Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀

tí òjìji yóò fi fò lọ,

èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá

àti sí òkè kékeré tùràrí.

7 Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;

kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

8 Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,

ki a lọ kúrò ní Lebanoni.

Àwa wò láti orí òkè Amana,

láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,

láti ibi ihò àwọn kìnnìún,

láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

9 Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

ìwọ ti gba ọkàn mi

pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,

pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.

10 Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!

Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,

òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

11 Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;

wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.

Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.

12 Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.

13 Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni

ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi,

14 nadi àti Safironi,

kalamusi àti kinamoni,

àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,

òjìá àti aloe

pẹ̀lú irú wọn.

15 Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè,

ìṣàn omi láti Lebanoni wá.

Olólùfẹ́

16 Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá

kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù!

Fẹ́ lórí ọgbà mi,

kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.

Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀

kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.

Olùfẹ́

5:1 Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.

Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;

mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.

Ọ̀rẹ́

Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,

àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.

Olólùfẹ́

2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.

Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.

“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,

àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,

orí mi kún fún omi ìrì,

irun mi kún fún òtútù òru.”

3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi

ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?

Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi

ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?

4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn

inú mi sì yọ́ sí i.

5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,

òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,

òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn

sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.

6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,

ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ

ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.

Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.

Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.

7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi

bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.

Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;

wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.

Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín

bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,

kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?

Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.

Ọ̀rẹ́

9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,

ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?

Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ

tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?

Olólùfẹ́

10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n

ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.

11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ

ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ

ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò.

12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà

ní ẹ̀bá odò tí ń sàn,

tí a fi wàrà wẹ̀,

tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.

13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí

tí ó sun òórùn tùràrí dídùn

Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì

ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.

14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,

tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká.

Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán

tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mabu

tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára.

Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,

tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.

16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀

ó wu ni pátápátá.

Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu.

Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.