Apá 11: Ìjọba Jotamu
Ìjọba Juda
758 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
32 Ní ọdún keje Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli, Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.
1 Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 2 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn.
35 Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò àwọn ènìyàn tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jotamu tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.
2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,
fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,
Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.
3 Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;
yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.
4 Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,
àwọn àfonífojì yóò sì pínyà,
bí idà níwájú iná,
bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
5 Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí,
àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli.
Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu?
Ǹjẹ́ Samaria ha kọ?
Kí ni àwọn ibi gíga Juda?
Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?
6 “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá,
bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà.
Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.
Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.
7 Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́
gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun,
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.
Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,
gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”
8 Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún,
èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:
èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò.
Èmi yóò ké bí akátá,
èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.
9 Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán;
ó sì ti wá sí Juda.
Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi,
àní sí Jerusalẹmu.
10 Ẹ má ṣe sọ ní Gati
ẹ má ṣe sọkún rárá.
Ní ilẹ̀ Beti-Ofra
mo yí ara mi nínú eruku.
11 Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú,
ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri.
Àwọn tí ó ń gbé ni Saanani
kì yóò sì jáde wá.
Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀;
a ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.
12 Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre,
ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.
13 Ìwọ olùgbé Lakiṣi,
dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára.
Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀
sí àwọn ọmọbìnrin Sioni,
nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.
14 Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀
fún Moreṣeti Gati.
Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.
15 Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa.
Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli
yóò sì wá sí Adullamu.
16 Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀
nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára,
sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún,
nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.
2:1 Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé
tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn!
Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde
nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é.
2 Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n,
àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n.
Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára
àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.
3 Nítorí náà, Olúwa wí pé:
“Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí,
nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là.
Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́,
nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.
4 Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín;
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé:
‘Ní kíkó a ti kó wọn tán;
Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi;
Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”
5 Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa,
tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.
6 “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí.
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;
kí ìtìjú má ṣe le bá wa.”
7 Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu:
“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?”
“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere
fún ẹni tí ń rìn déédé bí?
8 Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde
bí ọ̀tá sí mi.
Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀
kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,
bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
9 Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi
kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn,
ẹ̀yin sì ti gba ògo mi,
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.
10 Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ!
Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín,
nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́
yóò pa yín run,
àní ìparun kíkorò.
11 Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé,
‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’
òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí!
12 “Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu;
Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ.
Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn,
ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
13 Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn;
wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ.
Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn,
Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn.”
3 Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli. 4 Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Juda òkè àti nínú igbó àti ilé ìṣọ́, ó mọ ilé odi.
5 Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) òsùwọ̀n alikama àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.
6 Jotamu sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tó tọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
7 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jotamu, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti ti Juda. 8 Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. 9 Jotamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
37 (Ní ayé ìgbàanì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah láti dojúkọ Juda).
33 Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 34 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Ussiah ti ṣe.
36 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jotamu, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
38 Jotamu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi, ìlú ńlá ti baba rẹ̀. Ahasi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Ìjọba Israẹli
Ìjọba Peka
27 Ní ọdún kejìléláàádọ́ta Asariah ọba Juda, Peka ọmọ Remaliah di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ogún ọdún. 28 Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá.
29 Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria.