Ìjọba Israẹli

Ìparí Ìjọba Jeroboamu Kejì

809 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Ọba 14:25–27

25 Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Israẹli padà láti Lebo-Hamati sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jona ọmọ Amittai, wòlíì láti Gati-Heferi.

26 Olúwa ti rí ìpọ́njú Israẹli pé, ó korò gidigidi, nítorí kò sí ẹrú tàbí òmìnira tàbí olùrànlọ́wọ́ kan fún Israẹli. 27 Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Israẹli láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi.

Hosea Sọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli 801 ṣáájú ìbí Kristi

Ẹ̀bẹ̀ àkọ́kọ́ tí Hosea ṣe sí ẹ̀yà mẹ́wàá.

Hosea 1–3

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli.

2 Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.” 3 Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.

4 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin. 5 Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní àfonífojì Jesreeli.”

6  Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ruhama, nítorí pé, Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n. 7 Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”

8 Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-ruhama, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni 9 Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.

10 “Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ 11 Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.

2:1 “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àyànfẹ́ mi.’

2 “Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,

nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,

Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.

Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀

àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.

3 Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò,

Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.

Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,

Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀

Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.

4 Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀

nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́.

5 Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,

ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.

Ó wí pé, ‘Èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,

tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,

ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,

òróró mi àti ohun mímu mi.’

6 Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà,

Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.

7 Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;

yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.

Nígbà náà ni yóò sọ pé,

‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́

nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’

8 Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni

àti ẹni tó fún un ní ọkà,

ọtí wáìnì tuntun àti òróró

ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.

9 “Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,

èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.

Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà

ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.

10 Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn

lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀

kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi,

11 Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:

àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,

ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.

12 Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,

èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀,

Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,

àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.

13 Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀

nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali;

tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,

tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,”

ni Olúwa wí.

14 “Nítorí náà, èmi yóò tàn án,

Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀,

Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀

15 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,

Èmi yóò fi àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.

Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀

gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.

16 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,

ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’;

ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’

ni Olúwa wí.

17 Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀;

ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́.

18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú

fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti

àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.

Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́.

Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà

kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.

19 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé;

Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́,

ní ìfẹ́ àti àánú.

20 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́

ìwọ yóò sì mọ Olúwa.

21 “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,”

ni Olúwa wí;

“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn

àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;

22 ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,

wáìnì tuntun àti òróró lóhùn

Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.

23 Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà,

Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘Àánú gbà.’

Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’

‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”

3:1 Olúwa sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Olúwa sì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.”

2 Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan. 3 Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.”

4 Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan. 5 Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.