Àwọn Júù Padà Láti Ìgbèkùn (continued)

536 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 116–117

1 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;

ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.

2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,

èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.

3 Okùn ikú yí mi ká,

ìrora isà òkú wá sórí mi;

ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.

4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:

“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”

5 Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo;

Ọlọ́run wa kún fún àánú.

6 Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́

nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

7 Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ,

nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

8 Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi

kúrò lọ́wọ́ ikú,

ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,

àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,

9 nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa

ní ilẹ̀ alààyè.

10  Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,

“èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.

11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé,

“Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa

nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?

13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè

èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.

14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa

ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15 Iyebíye ní ojú Olúwa

àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;

èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;

ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ

èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.

18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa

ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,

19 nínú àgbàlá ilé Olúwa

ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.

Ẹ yin Olúwa.

117:1  Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;

ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.

2 Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,

àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.

Ẹ yin Olúwa!

Saamu 125

Orin fún ìgòkè.

1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,

tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.

2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká

láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú

kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;

kí àwọn olódodo kí ó máa ba à

fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

4 Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,

àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.

5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;

Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Saamu 127–128

Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

1 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà

àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;

bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.

2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù

láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;

bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:

ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.

4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.

5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;

ojú kì yóò tì wọ́n,

ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

Orin fún ìgòkè.

128:1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:

tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ

ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.

3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere

eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;

àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.

4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,

tí ó bẹ̀rù Olúwa.

5 Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,

kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre

Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.

6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.

Láti àlàáfíà lára Israẹli.

Saamu 134

Orin ìgòkè.

1 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,

gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,

tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.

2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,

kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.

3 Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé,

kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.