Èdìdì Kìíní: Ìhìnrere Ṣẹ́gun
A ṣí èdìdì kìíní. Ìran tí ó tẹ̀ lé e kéde ìṣẹ́gun ìhìnrere ní gbogbogbòò lórí àwọn Júù àti àwọn kèfèrí.
96 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!” 2 Mo sì wò ó, kíyèsi i, ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọfà kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun.
Èdìdì Kejì: A Tú Àwọn Júù Ká
A ṣí èdìdì kejì. Ó kéde àwọn inúnibíni oníkà àti títú àwọn Júù ká pátápátá lábẹ́ ìṣàkóso Trajan àti Hadrian (102–138).
3 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!” 4 Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde, a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn, a sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.
Èdìdì Kẹta: Àlàáfíà àti Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ohun Rere
A ṣí èdìdì kẹta. Ó kéde àlàáfíà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere ní àkókò ìṣàkóso ìdílé Septimius Severus (193–235).
5 Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. 6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òsùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òsùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.
Èdìdì Kẹrin: Ogun, Ìyàn àti Àjàkálẹ̀ Àrùn
A ṣí èdìdì kẹrin. Ó kéde àwọn ogun oníkà, ìyàn, inúnibíni àti àjàkálẹ̀ àrùn tí ó gbilẹ̀ ní àkókò ìṣàkóso Maximinus, Decius àti Valerian (255–271).
7 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, “Wá wò ó!” 8 Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan, orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.
Èdìdì Karùn-ún: Inúnibíni Ìkẹyìn Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Abọ̀rìṣà
A ṣí èdìdì karùn-ún. Ó kéde inúnibíni ìkẹyìn tí àwọn abọ̀rìṣà ṣe sí ẹ̀sìn Kristiani, àti ìbẹ̀rù àwọn Kristiani (286–301).
9 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú, 10 Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” 11 A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.
Èdìdì Kẹfà: A Bì Ẹ̀sìn Àwọn Abọ̀rìṣà Ṣubú
A ṣí èdìdì kẹfà. Ó ṣàpèjúwe àwọn ìdàrúdàpọ̀ ní Ilẹ̀ Ọba àwọn ará Romu nígbà ìbìṣubú ìkẹyìn ti ẹ̀sìn àwọn abọ̀rìṣà, àti fífi ìjọ Kristiani fìdí múlẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ́gun ní ipò rẹ̀. Apá ìran yìí tún tọ́ka sí ayọ̀ ayérayé ti àwọn ajẹ́rìíkú àkọ́kọ́, àti ìyìn tí wọ́n ń fi fún Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́-àgùntàn (323).
12 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13 àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í. 14 A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.
15 Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; 16 wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. 17 Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé; ta ni ó sì le dúró?”
7:1 Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. 2 Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, 3 wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” 4 Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.
5 Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
6 Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
7 Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
8 Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).
9 Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10 Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:
“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá
tí o jókòó lórí ìtẹ́,
àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”
11 Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12 Wí pe:
“Àmín!
Ìbùkún, àti ògo,
àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,
àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!
Àmín!”
13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”
14 Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”
Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15 Nítorí náà ni,
“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,
tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀;
ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si síji bò wọn.
16 Ebi kì yóò pa wọn mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;
bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn
tàbí oorukóoru kan.
17 Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn,
‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè.’
‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”
Èdìdì Keje: Áńgẹ́lì Méje Pẹ̀lú Ìpè
A ṣí èdìdì keje. Áńgẹ́lì méje pẹ̀lú ìpè méje farahàn ní ọ̀run. A kéde àdúrà ọpẹ́ àwọn Kristiani tí wọ́n ti wà ní ìsinmi nísinsìnyí, àti bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gba àdúrà wọn, pẹ̀lú ìparun tí àwọn aláìlàjú yóò mú wá sórí ilẹ̀ ọba náà.
1 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.
2 Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.
3 Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. 4 Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. 5 Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.
Ìpè Kìíní: Àwọn Orílẹ̀-Èdè Àríwá Gbé Ogun Wọlé
Àkókò tuntun ti ìbìṣubú agbára àwọn ará Romu, tí ó ti ń dá ọkùnrin ẹ̀ṣẹ̀ náà dúró títí di ìsinsìnyí, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífọn ìpè méje. Ìpè kìíní dún. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó tẹ̀ lé e ṣàpẹẹrẹ ṣáájú bí àwọn orílẹ̀-èdè aláìlàjú ní Àríwá yóò ṣe gbé ogun wọ Ilẹ̀ Ọba àwọn ará Romu (323–412).
6 Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.
7 Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀, Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ́ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ́ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jóná.
Ìpè Kejì: Àwọn Vandal Ṣẹ́gun
Ìpè kejì dún. Àwọn Vandal àti àwọn Alan lábẹ́ Genseric pa agbára ìṣèlú Ilẹ̀ Ọba àwọn ará Romu ní Ìwọ̀ Oòrùn run (395–455).
8 Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀; 9 àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.
Ìpè Kẹta: A Mú Omi Di Kíkorò
Ìpè kẹta dún. Èyí lè jẹ́ àpẹẹrẹ ṣáájú yíyọ Augustulus, olú ọba ìkẹyìn ti àwọn ará Romu ní Ìwọ̀ Oòrùn, kúrò ní ipò; tàbí ìyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́ tàbí ìwà ìbàjẹ́ àwọn olórí ìjọ tí wọ́n ń lé ipò; tàbí títàn àwọn èrò Augustine kálẹ̀, tí ó ti mú omi ìyè di kíkorò tí ó sì ti pa ìṣọ̀kan Kristiani run ju èrò ẹnikẹ́ni mìíràn lọ (455–476).
10 Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi. 11 A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.
Ìpè Kẹrin: Àṣẹ Ìkẹyìn Romu Dópin
Ìpè kẹrin dún. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ogun ní Itali láàárín àwọn tí ó ṣẹ́gun Romu, àwọn ọ̀gágun Justinian, àti àwọn Goth, àti dídá ìṣàkóso gómìnà àgbà ti Ravenna sílẹ̀, tí ó pa gbogbo àṣẹ Romu tí ó ṣẹ́ kù rẹ́, títí dé ọdún 606.
12 Angẹli kẹrin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ́ta oòrùn, àti ìdámẹ́ta òṣùpá, àti ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ́ta wọn lè ṣókùnkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.
A Mú Ọ̀nà Sílẹ̀ fún Ìyapa Ńlá Méjì Kúrò Nínú Ìgbàgbọ́
Àkókò mìíràn tí a kò lè gbàgbé nínú ìtàn aráyé bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí. Ìwà ìbàjẹ́ tí ó gbilẹ̀ láàárín àwọn Kristiani àti àìlera ìṣèlú ilẹ̀ ọba náà mú ọ̀nà sílẹ̀ fún ìyapa ńlá méjì kúrò nínú ìgbàgbọ́, tí yóò wà fún ọdún 1260, tí yóò sì dìde papọ̀ ní àwọn ilẹ̀ ọba ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn (606).
13 Mo sì wò, mo sì gbọ́ idì kan tí ń fò ni àárín ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn angẹli mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”