Ìkọlù Àkọ́kọ́ Sennakeribu
713 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Hesekiah ti fi òtítọ́ ṣe, Sennakeribu ọba Asiria wá ó sì gbógun ti Juda. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ara rẹ̀. 2 Nígbà tí Hesekiah rí i pé Sennakeribu ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lórí Jerusalẹmu, 3 Ó gbèrò pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ láti di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. 4 Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń sàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ náà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Asiria fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí. 5 Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta. Ó sì tún pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé ní ti ìlú ńlá Dafidi. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.
6 Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pè wọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dafidi. Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: 7 “Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Asiria àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ. 8 Agbára ẹran-ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, Olúwa Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekiah ọba Juda wí.
Hesekiah Juwọ́ Sílẹ̀, A sì Gba Aṣdodu
13 Ní ọdún kẹrìnlá tí Hesekiah jẹ ọba, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo ìlú olódi ti Juda ó sì pa wọ́n run. 14 Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah ọba Juda sì ránṣẹ́ yìí sí ọba Asiria ní Lakiṣi, wí pé, “Mo ti ṣẹ̀, padà lẹ́yìn mi: èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba Asiria sì bu fún Hesekiah ọba Juda ọ̀ọ́dúnrún (300) tálẹ́ǹtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ǹtì wúrà. 15 Hesekiah fún un ní gbogbo fàdákà tí a rí nínú ilé Olúwa àti nínú ìṣúra ilé ọba.
16 Ní àkókò yìí Hesekiah ọba Juda ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, kúrò àti ti òpó tí Hesekiah ọba Juda ti gbéró ó sì fi fún ọba Asiria.
1 Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o— 2 ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.
3 Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi, 4 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti. 5 Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi Ejibiti yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n. 6 Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Asiria! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”
Ìpè Àsọtẹ́lẹ̀ sí Jerusalẹmu
Ìpè àsọtẹ́lẹ̀ sí Jerusalẹmu nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sennakeribu wà ní ilẹ̀ náà.
1 Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
Fi ọdún kún ọdún
sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
2 Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
3 Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo,
Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká,
Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
4 Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.
5 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
6 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá
pẹ̀lú àrá àti ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá,
àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun.
7 Lẹ́yìn náà,
ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
tí ó sì dó tì í,
yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
bí ìran ní òru
8 àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun,
ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀;
tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè
tí ń bá òkè Sioni jà.
9 Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,
ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;
ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,
ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10 Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín:
ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì;
ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.
11 Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” 12 Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”
13 Olúwa wí pé:
“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
ọkùnrin kọ́ ni.
14 Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
15 Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
tí wọ́n sì rò pé,
“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
16 Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé,
“Òun kọ́ ló ṣe mí”?
Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
“Kò mọ nǹkan”?
17 Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
18 Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.
19 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:
àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
20 Aláìláàánú yóò pòórá,
àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—
21 àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.
22 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu:
“Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́;
ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23 Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn,
àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,
wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,
wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu
wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.
24 Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀;
gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”