A Pa Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Sennakeribu Run
710 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
8 Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Libina jà.
9 Nísinsin yìí, Sennakeribu sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tirakah, ọba Etiopia ti Ejibiti wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé, 10 “Sọ fún Hesekiah ọba Juda pé, má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jerusalẹmu a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Asiria.’ 11 Lóòótọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Asiria tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátápátá. Ìwọ yóò sì gbàlà? 12 Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gosani, Harani Reṣefu àti gbogbo ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13 Níbo ni ọba Hamati wa, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi, ti Hena, tàbí ti Iffa gbé wà?”
14 Hesekiah gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ síwájú Olúwa. 15 Hesekiah gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ń gbé ní àárín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. 16 Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Sennakeribu tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.
17 “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Asiria ti pa orílẹ̀-èdè wọ̀nyí run àti ilẹ̀ wọn. 18 Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn. 19 Nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkan ṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”
Saamu ti Asafu.
1 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
2 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
3 Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
4 Wọn kò ṣe wàhálà;
ara wọn mókun wọn sì lágbára.
5 Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
6 Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
7 Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n.
8 Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára,
wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
9 Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”
12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí,
ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
Ó jẹ́ ìnilára fún mi,
17 títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,
ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
àti ọkàn mi ṣì korò,
22 mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.
23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.
25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
àti ìpín mi títí láé.
27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run.
Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;
kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.
20 Nígbà náà Isaiah ọmọ Amosi rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Sennakeribu ọba Asiria. 21 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀,
“ ‘Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni
kẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu
mi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.
22 Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀?
Lórí ta ni ìwọ ti gbé ohùn rẹ
sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga?
Lórí ẹni mímọ́ ti Israẹli!
23 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ
ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.
Tì wọ sì wí pé,
“Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
àti ààyò igi firi rẹ̀.
Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀
sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀.
24 Mo ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,
mo sì mu omi níbẹ̀.
Pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi,
èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Ejibiti.”
25 “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?
Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.
Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;
nísinsin yìí mo ti mú wá sí ìkọjá
pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí
òkìtì àlàpà òkúta.
26 Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,
wọ́n ti dà á láàmú
wọ́n sì ti ṣọ́ di ìtìjú.
Wọ́n dàbí koríko igbó lórí pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbàsókè,
gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.
27 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ
dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí
lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi.
28 Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi
àti ìrora rẹ dé etí mi,
Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ
àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ,
èmi yóò mú ọ padà
nípa wíwá rẹ.’
29 “Èyí yóò jẹ́ àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:
“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,
àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú ìyẹn.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,
gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èso rẹ̀.
30 Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Juda
yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èso lókè.
31 Láti inú Jerusalẹmu ní àwọn ìyókù yóò ti wá
àti láti orí òkè Sioni ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sá àsálà.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe èyí.
32 “Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria:
“Kò ní wọ ìlú yìí
tàbí ta ọfà síbí.
Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú
àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.
33 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò padà;
kì yóò wọ ìlú ńlá yìí,
ni Olúwa wí.
34 Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí,
èmi yóò sì pa á mọ́ fún èmi tìkára mi àti fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.”
35 Ní alẹ́ ọjọ́ náà, angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Asiria. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà!
Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
1 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé,
ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”
6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
76:1 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá,
ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,
9 nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
36 Bẹ́ẹ̀ ni Sennakeribu ọba Asiria wọ àgọ́ ó sì padà, ó sì padà sí Ninefe ó sì dúró níbẹ̀.
37 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nisroki, ọmọkùnrin rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati Esarhadoni ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.