Àwọn Sáàmù Ìdààmú, Ní Pàtàkì Láti Àkókò Ìgbèkùn

Àwọn sáàmù tí a kọ ní àkókò ìdààmú àti ìpọ́njú ìjọ, ní pàtàkì nígbà ìgbèkùn ní Babeli.

539 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 137

1 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó

àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

2 Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,

tí ó wà láàrín rẹ̀.

3 Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn

tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,

àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá;

wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”

4 Àwa ó ti ṣe kọ orin

Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì

5 Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ

jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.

6 Bí èmi kò bá rántí rẹ,

jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;

bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú

olórí ayọ̀ mi gbogbo.

7 Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,

lára àwọn ọmọ Edomu,

àwọn ẹni tí ń wí pé,

“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”

8 Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;

ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ

bí ìwọ ti rò sí wa.

9 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ

tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Saamu 130

Orin fún ìgòkè.

1 Láti inú ibú wá ni

èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa

2 Olúwa, gbóhùn mi,

jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

3 Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,

Olúwa, tá ni ìbá dúró.

4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,

kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.

5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,

àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.

6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,

ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,

àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:

nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,

àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.

8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè

kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

Saamu 80

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.

1 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;

ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran.

Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù,

tàn jáde 2 níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.

Ru agbára rẹ̀ sókè;

wá fún ìgbàlà wa.

3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;

jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,

kí a bá à lè gbà wá là.

4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,

ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó

sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?

5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn

ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,

àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;

jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,

kí a ba à lè gbà wá là.

8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;

ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.

9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,

ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀

ó sì kún ilẹ̀ náà.

10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,

ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.

11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,

ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.

12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀

tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?

13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́

àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.

14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!

Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!

Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,

15 gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,

àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.

16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;

ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.

17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.

18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;

mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.

19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;

kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,

kí á ba à lè gbà wá là.

Saamu 77

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu.

1 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;

mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.

2 Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,

mo wá Olúwa;

ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀

ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.

3 Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,

mo sì kẹ́dùn;

mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.

4 Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,

mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

5 Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;

ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

6 mo rántí orin mi ní òru.

Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀,

ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.

7 “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?

Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?

8 Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé?

Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?

9 Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?

Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.

10 Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,

pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.

11 Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:

bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.

12 Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo,

pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.

13 Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.

Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?

14 Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;

ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.

15 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,

àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.

16 Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,

nígbà tí àwọn omi rí ọ,

ẹ̀rù bà wọ́n,

nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.

17 Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,

àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn;

ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.

18 Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì,

ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;

ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

19 Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun,

ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,

nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.

20 Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran

nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.