Àwọn Sáàmù Ìdààmú, Ní Pàtàkì Láti Àkókò Ìgbèkùn (continued)
Àwọn sáàmù tí a kọ ní àkókò ìdààmú àti ìpọ́njú ìjọ, ní pàtàkì nígbà ìgbèkùn ní Babeli.
539 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi.
1 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
2 láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,
3 lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
àti lára ohun èlò orin haapu.
4 Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
5 Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
6 Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
7 nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.
8 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
9 Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
tí ó dìde sí mi.
12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,
13 tí a gbìn sí ilé Olúwa,
Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
kankan nínú rẹ̀.”
93:1 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì le è yí.
2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
ìwọ wà títí ayérayé.
3 A ti gbé òkun sókè, Olúwa,
òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
ó ni ògo ju òkun rírú lọ
Olúwa ga ní ògo.
5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
Orin fún ìgòkè.
1 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4 Ọkàn wa kún púpọ̀
fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.