Àwọn Sáàmù Ìdààmú, Ní Pàtàkì Láti Àkókò Ìgbèkùn (continued)

Àwọn sáàmù tí a kọ ní àkókò ìdààmú àti ìpọ́njú ìjọ, ní pàtàkì nígbà ìgbèkùn ní Babeli.

539 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 49

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!

Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.

2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré

tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!

3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá

4 èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,

èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

5 Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?

Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,

6 àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,

tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.

7 Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀

padà tàbí san owó ìràpadà fún

Ọlọ́run.

8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye

kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,

9 ní ti kí ó máa wà títí ayé

láìrí isà òkú.

10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,

bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé

wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.

11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,

ibùgbé wọn láti ìrandíran,

wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́

ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó

gbàgbọ́ nínú ara wọn,

àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,

tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.

14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú

ikú yóò jẹun lórí wọn;

ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,

jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀.

Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,

isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.

15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà

kúrò nínú isà òkú,

yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.

16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.

Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.

17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,

ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú.

18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.

Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.

19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀

àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Saamu 53

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí mahalati. Maskili ti Dafidi.

1  Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé,

“Ọlọ́run kò sí.”

Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;

kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere.

2 Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run

sórí àwọn ọmọ ènìyàn,

láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,

tí ó sì ń wá Ọlọ́run.

3 Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,

wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;

kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

4 Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?

Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun

tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?

5 Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá

níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí,

nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká;

ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.

6 Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni!

Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,

jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!

Saamu 50

Saamu ti Asafu.

1 Olúwa, Ọlọ́run alágbára,

sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ

láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.

2 Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,

Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀

3 Ọlọ́run ń bọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,

iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,

àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.

4 Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,

kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.

5 “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi

àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”

6 Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,

nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni onídàájọ́.

7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:

èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.

8 Èmi kí yóò bá ọ wí

nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,

tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi

ní ìgbà gbogbo.

9 Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,

tàbí kí o mú òbúkọ láti

inú agbo ẹran rẹ̀

10 nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi

àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún (1,000) òkè.

11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá

àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.

12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,

nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo

tí ó wa ní inú rẹ̀.

13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí

mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,

kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.

15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,

èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:

“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,

tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?

17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,

ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.

18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,

ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.

19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,

ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.

20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,

ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.

21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;

ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,

ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,

èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.

Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.

23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,

kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”