Àwọn Sáàmù Ìdààmú, Ní Pàtàkì Láti Àkókò Ìgbèkùn (continued)

Àwọn sáàmù tí a kọ ní àkókò ìdààmú àti ìpọ́njú ìjọ, ní pàtàkì nígbà ìgbèkùn ní Babeli.

539 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 26–27

Ti Dafidi.

1 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,

nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,

mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa,

ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,

dán àyà àti ọkàn mi wò;

3 nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,

èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.

5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú

èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.

7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,

èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,

àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.

9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,

10 àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;

rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;

nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

Ti Dafidi.

27:1 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;

ta ni èmi yóò bẹ̀rù?

Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,

ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi

láti jẹ ẹran-ara mi,

àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,

wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,

ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;

bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,

nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,

òhun ni èmi yóò máa wá kiri:

kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa

ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,

kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,

kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú

òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;

níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;

yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè

ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;

èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;

èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Olúwa,

ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn,

8 Ọkàn mi wí pé, “Wá ojú u rẹ̀!”

Ojú rẹ, Olúwa, ni ti èmí ń wá.

9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,

má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;

ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,

Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,

háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.

10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,

Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,

kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú

nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,

nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,

wọ́n sì mí ìmí ìkà.

13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,

èmi yóò rí ìre Olúwa

ní ilẹ̀ alààyè.

14 Dúró de Olúwa;

kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le

àní dúró de Olúwa.

Saamu 36

Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa.

1  Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú

jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé,

ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí

níwájú wọn.

2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn

títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.

3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;

wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀.

4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:

wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára

wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,

òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.

6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,

àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;

ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.

7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!

Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.

8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;

ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.

9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:

nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n

àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!

11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,

kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.

12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:

a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!