Àwọn Sáàmù láti Ìgbà Ìjọba Dafidi, Tí Ọjọ́ Wọn Kò Dájú (continued)

Àwọn sáàmù tí Dafidi kọ lẹ́yìn tí ó di ọba, tí ọjọ́ tí ó kọ wọ́n àti àwọn ipò tí ó wà nígbà tí ó kọ wọ́n kò dájú.

1015 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

1  Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,

ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

2 nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun

ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?

Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

4  Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,

ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán

tí kò sì búra èké.

5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,

àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,

tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;

kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!

Kí ọba ògo le è wọlé.

8 Ta ni ọba ògo náà?

Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,

Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.

9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;

kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,

kí Ọba ògo le è wọlé wá.

10 Ta ni Ọba ògo náà?

Olúwa àwọn ọmọ-ogun

Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

Saamu 28–29

Ti Dafidi.

1 Ìwọ Olúwa,

mo ké pe àpáta mi.

Má ṣe kọ etí dídi sí mi.

Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,

èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.

2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,

bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,

bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè

sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ.

3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,

pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,

tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn

ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.

4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn

àti fún iṣẹ́ ibi wọn;

gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;

kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,

tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀

òun ó rún wọn wọlẹ̀

kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

6 Alábùkún fún ni Olúwa!

Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;

nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.

Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀

àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀

òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀.

9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;

di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Saamu ti Dafidi.

29:1 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,

ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.

2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;

sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

3 Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;

Ọlọ́run ògo sán àrá,

Olúwa san ara.

4 Ohùn Olúwa ní agbára;

ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.

5 Ohùn Olúwa fa igi kedari;

Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.

6 Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,

àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.

7 Ohùn Olúwa ń ya

bí ọwọ́ iná mọ̀nà.

8 Ohùn Olúwa ń mi aginjù.

Olúwa mi aginjù Kadeṣi.

9 Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,

ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.

Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;

Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.

11 Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;

bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Saamu 38

Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

1 Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.

2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,

ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.

3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;

kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.

4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;

wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́

nítorí òmùgọ̀ mi.

6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi

èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.

7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni

kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.

8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;

mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

9 Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;

ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;

bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.

11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,

àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.

12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;

àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,

wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;

àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.

14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,

àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;

ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.

16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;

nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,

ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;

àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.

20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi

àwọn ni ọ̀tá mi

nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.

21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!

Ọlọ́run mi, má ṣe jìnnà sí mi.

22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,

Olúwa, Olùgbàlà mi.