Àwọn Sáàmù láti Ìgbà Ìjọba Dafidi, Tí Ọjọ́ Wọn Kò Dájú (continued)

Àwọn sáàmù tí Dafidi kọ lẹ́yìn tí ó di ọba, tí ọjọ́ tí ó kọ wọ́n àti àwọn ipò tí ó wà nígbà tí ó kọ wọ́n kò dájú.

1015 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 120–122

Orin fún ìgòkè.

1 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,

ó sì dá mi lóhùn.

2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké

àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

3 Kí ni kí a fi fún ọ?

Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,

ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?

4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,

pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.

5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,

nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!

6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé

láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.

7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí;

ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

Orin fún ìgòkè.

121:1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—

níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?

2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,

ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;

ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,

kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;

Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán

tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo

yóò pa ọkàn rẹ mọ́

8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́

láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

122:1 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,

“Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.”

2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,

ìwọ Jerusalẹmu.

3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú

tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.

4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,

àwọn ẹ̀yà Olúwa,

ẹ̀rí fún Israẹli,

láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.

5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,

àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.

6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;

àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.

7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,

àti ìre nínú ààfin rẹ̀.

8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi

èmi yóò wí nísinsin yìí pé,

kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀.

9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,

èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

Saamu 124

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,”

kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

2 ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,

nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,

3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè

nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,

4 nígbà náà ni omi

wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,

5 nígbà náà ni agbéraga

omi ìbá borí ọkàn wa.

6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n

bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.

7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;

okùn já àwa sì yọ.

8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,

tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Saamu 131

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1 Olúwa àyà mi kò gbéga,

bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:

bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,

tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.

2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,

mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,

bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:

ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.

3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa

láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.

Saamu 133

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún

àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.

2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,

tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:

tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀.

3 Bí ìrì Hermoni

tí o sàn sórí òkè Sioni.

Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,

àní ìyè láéláé.