Ẹ̀kọ́ Bàbá Nípa Ọgbọ́n (continued)

984 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Òwe 2–3

1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,

tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,

2 tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n

tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,

3 àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,

tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye

4 bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà

tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.

5 Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,

ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

6 Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,

láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.

7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,

Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

8 Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́

Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

9 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,

àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.

10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ

ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.

11 Ìmòye yóò pa ọ mọ́

òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.

12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,

lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,

13 ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin

láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,

14 ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,

tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,

15 ọ̀nà ẹni tí ó wọ́

tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.

16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin,

àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,

17 ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀

tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.

18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú

ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.

19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà

bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.

20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere

kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.

21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà

àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.

22 Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà

a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.

3:1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.

Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.

2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,

ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.

3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé

so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,

kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.

4  Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere

ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ

má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ

òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

7  Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ

bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ

àti okun fún àwọn egungun rẹ.

9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,

pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,

10 nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya

àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.

11  Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa

má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,

12 nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí

bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,

ẹni tí ó tún ní òye sí i,

14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ

ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;

kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;

ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,

òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;

àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;

20 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,

àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,

má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.

22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,

àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.

23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,

ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.

24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,

nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.

25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,

tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.

26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,

kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,

nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.

28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,

“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”

nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.

29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,

ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.

30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,

nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.

31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan

tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà

ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.

33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.

34  Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,

ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.

35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,

ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.