Àwọn Òwe Solomoni (continued)

984 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Òwe 19–20

1 Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù

ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.

2 Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀,

tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.

3 Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;

síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.

4 Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;

ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5 Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,

ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

6 Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;

gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.

7 Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,

mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!

Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,

kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.

8 Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;

ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

9 Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà

ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10 Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,

mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.

11 Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;

fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12 Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,

ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13 Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,

aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,

ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.

15 Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,

ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

16 Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

17 Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá,

yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.

18 Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;

àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.

19 Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀;

bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.

20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,

ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,

ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

22 Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;

ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.

23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;

nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;

kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

25 Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;

bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.

26 Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde

òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.

27 Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,

tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.

28 Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,

ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.

29 A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;

àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.

20:1 Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle;

ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.

2 Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún;

ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.

3 Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà,

ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,

nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

5 Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn;

ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn,

ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.

7 Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù

ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́

yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.

9 Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,

mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

10 Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ

Olúwa kórìíra méjèèjì.

11 Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀

nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

12 Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran

Olúwa ni ó dá méjèèjì.

13 Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà.

Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

14 “Kò dára, kò dára!” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí;

nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán,

yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.

15 Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ,

ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.

16 Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;

mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.

17 Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn,

ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.

18 Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn

bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.

19 Olófòófó a máa tú àṣírí

nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.

20 Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,

ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

21 Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀

kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.

22 Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.”

Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.

23 Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké.

Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

24 Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn.

Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?

25 Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá

nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

26 Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;

Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

27 Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn

a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

28 Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,

nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

29 Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn,

ewú orí ni iyì arúgbó.

30 Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ,

pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.