Àwọn Òwe Solomoni

984 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Òwe 10–11

1 Àwọn òwe Solomoni.

Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn,

ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

2 Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè,

ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

3 Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo,

ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

4 Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,

ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.

5 Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

6 Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo,

ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

7 Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún,

ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8 Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,

ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

9 Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu,

ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10 Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn,

aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,

ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

12 Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,

ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

13 Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,

ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

14 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,

ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

15 Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,

ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

16 Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn,

ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

17 Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.

18 Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́

ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

19 Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù

ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

20 Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà,

ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.

21 Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,

ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

22 Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,

kì í sì í fi ìdààmú sí i.

23 Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú,

ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

24 Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;

olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25 Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,

ṣùgbọ́n olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26 Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,

ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28 Ìrètí olódodo ni ayọ̀,

ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.

29 Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo,

ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

30 A kì yóò fa olódodo tu láéláé,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

31 Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,

ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

32 Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà,

ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

11:1 Olúwa kórìíra òsùwọ̀n èké,

ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.

2 Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé,

ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

3 Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀,

ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.

4 Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú,

ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

5 Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn,

ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.

6 Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là,

ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.

7 Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun;

gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.

8 A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀,

ibi wá sórí ènìyàn búburú.

9 Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,

ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.

10 Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀;

nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.

11 Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga:

ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

13 Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀

ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.

14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú

ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.

15 Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu,

ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.

16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìn

ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

17 Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore

ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18 Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ

ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

19 Olódodo tòótọ́ rí ìyè

ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

20 Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú

ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

21 Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà,

ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà.

22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀

ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.

23 Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere

ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.

24 Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;

òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.

25 Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;

ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.

26 Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́

ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.

27 Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere

ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.

28 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;

ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.

29 Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán

aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n.

30 Èso òdodo ni igi ìyè

ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

31  Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé

mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!