Ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Tẹmpili
1015 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
2 Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. 3 Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000). 4 Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. 5 Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
6 Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni:
Laadani àti Ṣimei.
8 Àwọn ọmọ Laadani
Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
9 Àwọn ọmọ Ṣimei:
Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn.
Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.
10 Àti ọmọ Ṣimei:
Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.
11 Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.
12 Àwọn ọmọ Kohati:
Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.
13 Àwọn ọmọ Amramu.
Aaroni àti Mose.
A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé. 14 Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.
15 Àwọn ọmọ Mose:
Gerṣomu àti Elieseri.
16 Àwọn ọmọ Gerṣomu:
Ṣubaeli sì ni alákọ́kọ́.
17 Àwọn ọmọ Elieseri:
Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́.
Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.
18 Àwọn ọmọ Isari:
Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19 Àwọn ọmọ Hebroni:
Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì,
Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20 Àwọn ọmọ Usieli:
Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.
21 Àwọn ọmọ Merari:
Mahili àti Muṣi.
Àwọn ọmọ Mahili:
Eleasari àti Kiṣi.
22 Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.
23 Àwọn ọmọ Muṣi:
Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa. 25 Nítorí pé Dafidi ti sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé, 26 àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀.” 27 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa. 29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òsùwọ̀n. 30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. 31 Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.
32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.
24:1 Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni.
Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. 2 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 3 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. 4 A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. 5 Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.
6 Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
7 Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu,
èkejì sí Jedaiah,
8 ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu,
ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu,
9 ẹ̀karùnún sì ni Malkiah,
ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini,
10 èkeje sì ni Hakosi,
ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah,
11 ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua,
ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,
12 ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu,
ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu,
13 ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa,
ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,
14 ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah,
ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri,
15 ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri,
èkejìdínlógún sì ni Hafisesi,
16 ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah,
ogún sì ni Jeheskeli,
17 ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini,
ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,
18 ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah,
ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.
19 Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.
20 Ìyókù àwọn ọmọ Lefi.
Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli
láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubaeli; Jehdeiah.
21 Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.
22 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti;
láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.
23 Àwọn ọmọ Hebroni:
Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin.
24 Àwọn ọmọ Usieli: Mika;
nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.
25 Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi;
nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.
26 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi.
Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.
27 Àwọn ọmọ Merari.
Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.
28 Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
29 Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.
30 Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti.
Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
31 Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké.