Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Paulu sí àwọn aláìkọlà àti àwọn ètò rẹ̀
Ní báyìí tí Paulu ti parí àwọn apá lẹ́tà rẹ̀ tó dá lórí ẹ̀kọ́ àti ìgbé ayé, ó yí àfiyèsí rẹ̀ ní pàtàkì sí àwọn aláìkọlà, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù. Ó dá a lójú pé wọ́n kún fún oore àti ìmọ̀ ète Ọlọ́run fún wọn débi pé wọ́n lè máa bá ara wọn wí. Síbẹ̀, ó fi ìgboyà kọ̀wé sí wọn nítorí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aposteli, èyí tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí ó lè mú àwọn aláìkọlà wá sí ìgbàgbọ́, àwọn tí ó ń fi rú ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run nísinsìnyí. Ó ń ṣògo nínú àṣeyọrí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, bí Kristi ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, tí ó sì ń fi àwọn àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá fìdí ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ tí a rán an múlẹ̀ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ìtara rẹ̀ láti wàásù ìhìnrere ní ibi tí a kò tí ì mọ̀ ọ́n ti dí i lọ́wọ́ láti ṣèbẹ̀wò sí Romu, níbi tí a ti gbìn ín sí tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ní báyìí tí kò sí iṣẹ́ mìíràn fún un láti ṣe, ó ní ìrètí láti rí wọn nígbà tí ó bá ń lọ sí Spania, àti láti gbádùn àjọṣepọ̀ wọn ní ọ̀nà àjò náà. Ó mẹ́nuba àjò tí ó gbèrò láti lọ sí Jerusalẹmu, láti gbé ọrẹ owó àwọn aláìkọlà tí ó mú wá sí ìgbàgbọ́ lọ fún àwọn Júù tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ ní Jerusalẹmu. Ó ní ìrètí pé èyí yóò mú kí wọ́n bá ara wọn rẹ́, nítorí pé, bí àwọn aláìkọlà ti mọ àwọn ohun ẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn Júù, ó yẹ kí wọ́n san án padà fún wọn nípa àwọn ohun ti ara. Ó tún sọ pé òun pinnu láti ṣèbẹ̀wò sí wọn lẹ́yìn tí òun bá ti fi ọrẹ owó náà jíṣẹ́, pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn àti ìbùkún ìhìnrere Kristi. Ó rọ̀ wọ́n láti gbàdúrà gidigidi kí a lè gbà á lọ́wọ́ àwọn Júù aláìgbàgbọ́ tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á run, àti kí ọrẹ owó tí òun mú wá lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristiani. Ó parí pẹ̀lú ìrètí rẹ̀ láti rí wọn, kí òun àti àwọn lè jèrè agbára nípa pípín àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí, ó sì súre fún wọn.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
14 Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. 15 Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run 16 láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́.
17 Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. 18 Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi, 19 nípa agbára iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìyìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 20 Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. 21 Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,
àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.”
22 Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa.
23 Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí, tí èmi sì ti ń pòǹgbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti bẹ́ yín wò, 24 mo gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí Spania. Èmi yóò rí i yín ní ọ̀nà àjò mi, àti pé ẹ ó mú mi já ọ̀nà níbẹ̀ láti ọ̀dọ̀ yín lọ, lẹ́yìn tí mo bá gbádùn ẹgbẹ́ yín fún ìgbà díẹ̀. 25 Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ sí Jerusalẹmu láti sé ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀. 26 Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu. 27 Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ. 28 Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti ṣe èyí tán, tí mo bá sì di èdìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò ti ọ̀dọ̀ yín lọ sí Spania. 29 Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún ìyìnrere Kristi.
30 Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nítorí Olúwa wa Jesu Kristi, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fún mi. 31 Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Judea àti kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo ní sí Jerusalẹmu le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀, 32 kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti kí èmi lè ní ìtura pọ̀ pẹ̀lú yín. 33 Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
Paulu gbóríyìn fún Febe ó sì kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀
Paulu gbóríyìn fún Febe, ẹni tí ó gbé lẹ́tà yìí lọ, ó sì bẹ àwọn Kristiani ní Romu pé kí wọ́n ràn án lọ́wọ́. Ó kí Akuila àti Priskilla, tí ó yìn gidigidi, àti ìjọ tí ó wà ní ilé wọn. Ó kí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ Kristiani tí wọ́n ti ń gbé ní Romu báyìí, tí ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wọn jẹ́ àwọn tí òun fúnra rẹ̀ yí padà sí ìgbàgbọ́.
1 Mo fi Febe arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díákónì nínú ìjọ tí ó wà ní Kenkerea. 2 Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.
3 Ẹ kí Priskilla àti Akuila, àwọn tí ó ti jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jesu. 4 Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í ṣe èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.
5 Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń péjọpọ̀ ní ilé wọn.
Ẹ kí Epenetu ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di ti Kristi ní orílẹ̀-èdè Asia.
6 Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ṣe làálàá púpọ̀ lórí wa.
7 Ẹ kí Androniku àti Junia, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrín àwọn aposteli, wọ́n sì ti wà nínú Kristi ṣáájú mi.
8 Ẹ kí Ampliatu, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.
9 Ẹ kí Urbani, alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Kristi àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Staki.
10 Ẹ kí Apelle, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kristi.
Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Aristobulu.
11 Ẹ kí Herodioni, ìbátan mi.
Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Narkissu tí wọ́n wá nínú Olúwa.
12 Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.
Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.
13 Ẹ kí Rufusi, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀lú.
14 Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Hermesi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.
15 Ẹ kí Filologu, àti Julia, Nereu, àti arábìnrin rẹ̀, àti Olimpa, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.
16 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.
Gbogbo ìjọ Kristi kí yín.
Ẹ yẹra fún àwọn tí ń fa ìyapa
Paulu tún kìlọ̀ fún wọn láti yẹra fún ìyapa àti àwọn ènìyàn tí ń fà á. Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi nípa wíwàásù ẹ̀kọ́ rẹ̀, èrè ayé nìkan ni wọ́n ń lépa; níwọ̀n bí wọn kò sì ti ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ dídùn àti ìpọ́nni tan ọkàn àwọn Kristiani tuntun tí kò fura jẹ tàbí mú wọn ṣìnà. Ó yọ̀ nítorí ìgbọràn wọn nísinsìnyí, ó sì rọ̀ wọ́n láti máa bá a lọ ní mímọ ohun tí ó dára àti ṣíṣe é, kí wọ́n sì jẹ́ mímọ́, tàbí aláìlẹ́ṣẹ̀, nípa ibi: ìyẹn ni pé kí wọ́n yẹra fún gbogbo ẹ̀kọ́ èké àti gbogbo àpẹẹrẹ búburú. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ìparun yóò dé kánkán sórí àwọn aṣojú Satani tí ń fa ìyapa sínú ìjọ, ó sì parí pẹ̀lú ìbùkún rẹ̀.
17 Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. 18 Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà. 19 Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.
20 Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.
Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.
Ìkíni àti ògo fún Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n kan ṣoṣo
Nínú àfikún lẹ́tà náà, Paulu rán ìkíni àwọn ènìyàn mélòó kan tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó ṣe àkótán ohun gbogbo nípa fífi ògo fún Ọlọ́run, ẹni tí òun nìkan ní agbára láti fìdí wọn múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Kristi láìsí Òfin Mose. Èyí jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ nígbà kan rí, tí a pa mọ́ ní àṣírí (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa pípe àwọn aláìkọlà), ṣùgbọ́n nísinsìnyí a ti sọ ọ́ di mímọ̀ nípa àṣẹ Ọlọ́run ayérayé tí a fi hàn fún Paulu, kí gbogbo orílẹ̀-èdè lè mọ ìgbọràn tí ìgbàgbọ́ ń mú wá nípasẹ̀ ìwàásù rẹ̀, kí wọ́n sì gbàgbọ́ kí wọ́n sì gbọràn. “Kí ògo wà fún Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n kan ṣoṣo títí láé.”
21 Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín.
22 Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.
23 Gaiusi, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́.
Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.
25 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, 26 ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; 27 kí ògo wà fún Ọlọ́run, ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.