Paulu Kọ̀wé sí Filemoni

Paulu kọ lẹ́tà rẹ̀ sí Filemoni ọ̀rẹ́ rẹ̀, láti bẹ̀ ẹ́ nítorí Onesimu ẹrú rẹ̀, ẹni tí ó ti sá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ sí Romu. Ní ìlú náà ni Onesimu ti di Kristiani nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Paulu.

62 lẹ́yìn ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Paulu Kí Filemoni

Níwọ̀n bí ó ti ń kọ̀wé lórí ọ̀ràn àdáni, Paulu bá Filemoni sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, kì í ṣe pẹ̀lú ipò àti àṣẹ aposteli. Timotiu darapọ̀ mọ́ ọn láti kí Filemoni, Affia olùfẹ́, Arkippu (Kolosse 4:17), àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀. Paulu súre fún wọn. Ó sọ fún Filemoni pé òun máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nínú àdúrà òun fún ìdàgbàsókè ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jesu Kristi àti ìfẹ́ rẹ̀ sí àwọn arákùnrin Kristiani. Ó tún gbàdúrà pé pípín tí ó ń pín nínú ọ̀làwọ́ rẹ̀, èyí tí í ṣe èso ìgbàgbọ́ ńlá, lè mú kí àwọn ẹlòmíràn mọ gbogbo ìwà rere tí ó wà nínú rẹ̀ nínú Kristi Jesu. Nítorí àwọn fúnra wọn ní ayọ̀ àti ìtùnú ńlá nínú ìfẹ́ rẹ̀, pàápàá nítorí àwọn ènìyàn mímọ́ tí wọ́n jẹ́ òtòṣì, tí a lé kúrò ní ilé wọn nítorí orúkọ Kristi, tí wọ́n ń lọ káàkiri láti wàásù ìhìnrere, tí ọrọ̀ Filemoni sì ti mú ìrọ̀rùn bá.

Filemoni 1:1–7

1 Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa,

Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, 2 sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:

3  Oore-ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.

4  Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, 5 nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. 6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. 7 Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.

Paulu Bẹ̀bẹ̀ nítorí Onesimu

Paulu sọ pé, nítorí ìfẹ́ tí òun ní sí Filemoni fún àwọn iṣẹ́ inú rere àti ọ̀làwọ́ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi òun lè pàṣẹ fún un láti ṣe ohun tí ó tọ́ nínú ọ̀ràn tí òun fẹ́ gbé dìde, òun yàn láti bẹ̀ ẹ́ dípò bẹ́ẹ̀. Ó fi ìfẹ́ tí òun fúnra rẹ̀ ní sí Filemoni àti ìfẹ́ tí Filemoni ti fi hàn sí àwọn ènìyàn mímọ́ bẹ̀ ẹ́ nítorí Onesimu, ọmọ òun, ẹni tí òun ti bí sí ìṣẹ̀dá tuntun nípa ẹ̀mí, tí òun sì ti rán padà gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ti fẹ́. Paulu bẹ̀ ẹ́ pé, “Nítorí náà, gbà á sínú agbo ilé rẹ. Ó dà bí ẹni pé òun ni ọkàn mi gan-an, ọmọ mi, apá kan ara mi. Ó wúlò fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi ìbá fi í pamọ́ lọ́dọ̀ mi láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, èmi tí í ṣe baba ìwọ fúnra rẹ nípa ẹ̀mí, nígbà tí mo wà nínú ẹ̀wọ̀n nítorí ìhìnrere, àti láti ṣe ohun tí ìwọ ìbá ṣe bí o bá wà ní Romu. Ṣùgbọ́n láìmọ èrò rẹ lórí ọ̀ràn náà, èmi kò fẹ́ fi í pamọ́, kí inú rere tí o fi hàn mí nípa dídárí jì í má bàa jẹ́ ti ìfipámúni, bí kò ṣe ti ìfẹ́ inú rẹ fúnra rẹ. Nítorí ó lọ kúrò fún ìgbà díẹ̀ kí, nípa ètò Ọlọ́run, a lè dá a padà fún ọ títí láé: kì í ṣe bí ẹrú mọ́, bí kò ṣe bí arákùnrin olùfẹ́ nínú Olúwa. Mo fẹ́ràn rẹ̀ ní pàtàkì, ṣùgbọ́n mélòómélòó ni ìwọ yóò fẹ́ràn rẹ̀ tó, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ àti ọ̀kan nínú agbo ilé rẹ, tí ó sì ti di ọmọ ẹgbẹ́ ìdílé rẹ ti ọ̀run nísinsìnyí, ìyẹn ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ. Bí o bá kà mí sí alábàápín nínú ìfẹ́ rẹ, gbà á bí ìwọ yóò ṣe gbà mí, níwọ̀n bí ó ti dà bí ẹni pé ó jẹ́ apá kan ara mi, àti pé ní gbígbà á, èmi ni ò ń gbà. Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ tàbí tí ó jẹ ọ́ ní ohunkóhun, kọ gbogbo rẹ̀ sí mi lọ́rùn. Èmi yóò san gbogbo ohun tí ó jẹ ọ́, mo sì fi ọwọ́ ara mi kọ ìlérí pé èmi yóò san án padà fún ọ, nítorí èmi kò fẹ́ kí o ṣe ojúrere yìí nítorí bí gbèsè tí o jẹ mí ṣe pọ̀ tó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ jẹ mí ní ìwọ fúnra rẹ, ìgbésí ayé rẹ gẹ́gẹ́ bí Kristiani. Nítorí náà, jẹ́ kí n rí àǹfààní díẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ nínú Olúwa: tẹ́ ìfẹ́ jíjinlẹ̀ ọkàn mi lọ́rùn nínú èyí, kí o sì gbà á padà sínú agbo ilé rẹ. Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìwọ yóò ṣègbọràn, láti inú ohun tí mo mọ̀ nípa ìwà rere rẹ gẹ́gẹ́ bí Kristiani, mo kọ̀wé sí ọ, ní ìdánilójú kíkún pé ìwọ yóò ṣe ju ohun tí mo béèrè lọ pàápàá.” Ó rán ìkíni Epafira, ìránṣẹ́ wọn, àti ti àwọn mìíràn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì parí pẹ̀lú ìbùkún rẹ̀ fún Filemoni àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.

Filemoni 1:8–25

8 Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, 9 síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi. 10  Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. 11 Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.

12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. 13 Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìnrere 14 ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. 15 Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé. 16 Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.

17 Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí. 18 Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ. 20 Èmi ń fẹ́ arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi. 21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.

22 Ó ku ohun kan, ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23 Epafira, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kristi Jesu kí ọ. 24  Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi.

25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.