Àsọtẹ́lẹ̀ Ohun Tí Yóò Ṣẹlẹ̀ sí Paṣuri

609 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jeremiah 20

1 Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. 2 Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa. 3  Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “Orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà. 4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n. 5 Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli. 6 Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”

7 Olúwa, o tàn mí jẹ́,

o sì ṣẹ́gun.

Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,

gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.

8 Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta

èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.

Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù

àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.

9 Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ

tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi

nínú egungun mi,

agara dá mi ní inú mi

nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.

10 Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,

ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo.

Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!

Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró

kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,

bóyá yóò jẹ́ di títàn,

nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,

àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11 Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù.

Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,

wọn kì yóò sì borí.

Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.

Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò

tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní,

jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,

nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13 Kọrin sí Olúwa!

Fi ìyìn fún Olúwa!

Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní

lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

14 Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!

Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.

15 Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,

tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,

“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”

16 Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú

tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú

Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,

ariwo ogun ní ọ̀sán.

17 Nítorí kò pa mí nínú,

kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi,

kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.

18 Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,

láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀

àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?

Àsọtẹ́lẹ̀ Ohun Tí Yóò Ṣẹlẹ̀ sí Ṣallumu àti Jehoiakimu

Jeremiah 22:1–23

1 Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin ọba Juda, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀: 2 ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ ọba Juda, tí ó jókòó ní ìtẹ́ Dafidi, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí. 3 Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí. 4 Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 5 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

6 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda,

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi,

gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni,

dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,

àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

7 Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ,

olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,

wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀,

wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.

8 “Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’ 9 Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”

10 Nítorí náà má ṣe sọkún nítorí ọba tí ó ti kú tàbí ṣọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,

ṣùgbọ́n ẹ sọkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú

nítorí kì yóò padà wá mọ́

tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.

11 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́. 12 Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”

13 “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo,

àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́

tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán

láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.

14 Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi

àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,

ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’

A ó sì fi igi kedari bò ó,

a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.

15 “Ìwọ ó ha jẹ ọba

kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari?

Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?

Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo,

nítorí náà ó dára fún un.

16 Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní,

ohun gbogbo sì dára fún un.

Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?”

ni Olúwa wí.

17 “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ

wà lára èrè àìṣòótọ́

láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀

ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”

18 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:

wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’

Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:

wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’

19 A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè

Jerusalẹmu.”

20 “Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta,

kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani,

kí o kígbe sókè láti Abarimu,

nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.

21 Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,

ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’

Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,

ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.

22 Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,

gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn,

nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́

nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.

23 Ìwọ tí ń gbé ‘Lebanoni,’

tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kedari,

ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,

ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!