Iṣẹ́ Kejì Tí A Yàn fún Nehemiah àti Àwọn Àtúnṣe Rẹ̀ (continued)

Iṣẹ́ kejì tí a yàn fún Nehemiah, àti àtúnṣe tí ó ṣe.

444 sí 433 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Nehemiah 11:1–12:9

1 Nísinsin yìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jerusalẹmu, àwọn ènìyàn tókù sì dìbò láti mú ẹnìkọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tókù yóò dúró sí àwọn ìlú u wọn. 2 Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jerusalẹmu.

3  Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà. 4 Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu).

Nínú àwọn ọmọ Juda:

Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;

5 àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo.

6 Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rinlénírinwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

7 Nínú àwọn ìran Benjamini:

Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaiah, 8 àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.

9 Joẹli ọmọ Sikri ni olórí òṣìṣẹ́ wọn, Juda ọmọ Hasenuah sì ni olórí agbègbè kejì ní ìlú náà.

10 Nínú àwọn àlùfáà:

Jedaiah; ọmọ Joiaribu; Jakini;

11 Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run, 12 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹmpili jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnlélógún (822) ọkùnrin:

Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaiah, ọmọ Amisi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah, 13 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin:

Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahsai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Immeri, 14 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin jẹ́ méjìdínláàádóje (128).

Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sabdieli ọmọ Hagedolimu.

15 Láti inú àwọn ọmọ Lefi:

Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ọmọ Bunni;

16 Ṣabbetai àti Josabadi, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Lefi, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;

17 Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, adarí tí ó ń ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà;

Bakbukiah ẹnìkejì láàrín àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀;

àti Abida ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

18 Àwọn ọmọ Lefi nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284).

19 Àwọn aṣọ́nà:

Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172) ọkùnrin.

20 Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀.

21 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.

22 Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run. 23 Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn.

24 Petahiah ọmọ Meṣesabeli, ọ̀kan nínú àwọn Sera ọmọ Juda ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.

25 Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Juda tí ń gbé Kiriati-Arba, àti àwọn ìletò agbègbè e rẹ̀, ní Diboni àti ìletò rẹ̀, ní Jekabseeli. 26 Ní Jeṣua, ní Molada, ní Beti-Peleti 27 ní Hasari-Ṣuali, ní Beerṣeba àti àwọn agbègbè rẹ̀. 28 Ní Siklagi, ní Mekona àti àwọn ìletò rẹ̀, 29 ní Ẹni-Rimoni, ní Sora, ní Jarmatu, 30 Sanoa, Adullamu àti àwọn ìletò o wọn, ní Lakiṣi àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Aseka àti àwọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Beerṣeba títí dé àfonífojì Hinnomu.

31 Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀. 32 Ní Anatoti, Nobu àti Ananiah, 33 ní Hasori Rama àti Gittaimu, 34 ní Hadidi, Seboimu àti Neballati, 35 ní Lodi àti Ono, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.

36 Nínú ìpín àwọn ọmọ Lefi ni Juda tẹ̀dó sí Benjamini.

12:1 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tí ó bá Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua padà:

Seraiah, Jeremiah, Esra,

2 Amariah, Malluki, Hattusi,

3 Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,

4 Iddo, Ginetoni, Abijah,

5 Mijamini, Moadiah, Bilgah,

6 Ṣemaiah, Joiaribu, Jedaiah,

7 Sallu, Amoki, Hilkiah, àti Jedaiah.

Wọ̀nyí ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jeṣua.

8 Àwọn ọmọ Lefi ni Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda àti Mattaniah ẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ni wọn ṣe àkóso orin ìdúpẹ́. 9 Bakbukiah àti Unni, àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró sí òdìkejì wọn nínú ìsìn.

Nehemiah 12:44–13:3

44 Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, nítorí inú àwọn ará a Juda yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́. 45 Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dafidi àti Solomoni ọmọ rẹ̀ ti pàṣẹ fún wọn. 46 Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ní ìgbà Dafidi àti Asafu, ni àwọn atọ́nisọ́nà ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 47 Nítorí náà ní ìgbà ayé Serubbabeli àti Nehemiah, gbogbo Israẹli ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi tókù, àwọn ọmọ Lefi náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀ fún wọn.

13:1  Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé. 2 Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí. (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún.) 3 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì ènìyàn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrín àwọn Israẹli.

Saamu 1

1  Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,

tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,

ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa

àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,

tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀

tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.

Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!

Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà

tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,

ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.