Mose Gun Òkè Nebo Láti Kú

1451 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Deuteronomi 32:48–52

48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Mose pé, 49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. 50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. 51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”

Mose Súre fún Àwọn Ènìyàn

Deuteronomi 33

1 Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú. 2 Ó sì wí pé,

“Olúwa ti Sinai wá,

ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá

ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.

Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá

láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.

3 Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,

gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.

Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,

àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,

4 òfin tí Mose fi fún wa,

ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.

5 Òun ni ọba lórí Jeṣuruni

ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,

pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

6 “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,

tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”

7 Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:

“Olúwa gbọ́ ohùn Juda

kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.

Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,

kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”

8 Ní ti Lefi ó wí pé,

“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà

pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.

Ẹni tí ó dánwò ní Massa,

ìwọ bá jà ní omi Meriba.

9 Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,

‘Èmi kò buyì fún wọn.’

Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,

tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,

ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,

ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.

10 Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀

àti Israẹli ní òfin rẹ̀.

Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀

àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.

11 Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa,

kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;

àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,

kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

12 Ní ti Benjamini ó wí pé,

“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,

òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,

ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”

13 Ní ti Josẹfu ó wí pé,

“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,

fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì

àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;

14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá

àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;

15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì

àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;

16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀

àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.

Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,

lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.

17 Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;

ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.

Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,

pàápàá títí dé òpin ayé.

Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu,

àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.”

18 Ní ti Sebuluni ó wí pé,

“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,

àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.

19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè

àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,

wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,

nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”

20 Ní ti Gadi ó wí pé,

“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!

Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,

ó sì fa apá ya, àní àtàrí.

21 Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;

ìpín olórí ni a sì fi fún un.

Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,

ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,

àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”

22 Ní ti Dani ó wí pé,

“Ọmọ kìnnìún ni Dani,

tí ń fò láti Baṣani wá.”

23 Ní ti Naftali ó wí pé,

“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run

àti ìbùkún Olúwa;

yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”

24 Ní ti Aṣeri ó wí pé,

“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;

jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀

kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.

25 Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,

agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.

26 “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,

ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ

àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.

27 Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,

àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.

Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,

ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’

28 Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,

orísun Jakọbu nìkan

ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,

níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.

29 Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,

ta ni ó dàbí rẹ,

ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?

Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀

àti idà ọláńlá rẹ̀.

Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,

ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

Mose Kú, Àwọn Ènìyàn sì Ṣọ̀fọ̀

Deuteronomi 34

1 Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani, 2 gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun Ńlá, 3 gúúsù àti gbogbo àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari. 4 Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.”

5 Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Moabu, bí Olúwa ti wí. 6 Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà. 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. 8 Àwọn ọmọ Israẹli sọkún un Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Mose parí.

9 Joṣua ọmọ Nuni kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Mose ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lé e lórí. Àwọn ọmọ Israẹli sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

10  Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú, 11 tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà. 12 Nítorí kò sí ẹni tí ó tí ì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Mose fihàn ní ojú gbogbo Israẹli.