Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Mika Ṣe Àtìlẹ́yìn fún Àtúnṣe Hesekiah (continued)

722 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Mika 6–7

1 Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí:

“Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá;

sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.

2 “Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa;

gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé.

Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́;

òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.

3 “Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?

Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.

4 Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,

mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá.

Mo rán Mose láti darí yín,

bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.

5 Ìwọ ènìyàn mi,

rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò

àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn.

Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali,

kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

6 Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa

tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga?

Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,

pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?

7 Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò,

tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró?

Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi,

èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?

8 Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára,

àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?

Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú,

àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

9 Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà,

láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.

“Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án.

10 Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà

ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀,

àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?

11 Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́

pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú,

pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?

12 Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá;

àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké

àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?

13 Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́,

láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

14 Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó;

ìyàn yóò wà láàrín rẹ.

Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu,

nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.

15 Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè

ìwọ yóò tẹ olifi,

ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ;

ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.

16 Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́,

àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu,

tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn,

nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun

àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà;

ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”

7:1 Ègbé ni fún mi!

Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ,

ìpèsè ọgbà àjàrà;

kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ,

kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.

2 Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà,

kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́;

gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀,

olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.

3 Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú;

àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn,

àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀

alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́,

gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.

4 Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún,

ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ.

Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé,

àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò.

Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.

5 Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́;

ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan.

Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni

tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.

6  Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀,

ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀,

aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀,

ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.

7 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa,

èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi;

Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.

8 Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi.

Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde.

Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn

Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.

9 Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i,

èmi yóò faradà ìbínú Olúwa,

títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò,

tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi.

Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;

èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.

10 Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i

ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé,

“Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?”

Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀;

nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀

bí ẹrẹ̀ òpópó.

11 Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé,

ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.

12 Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ

láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti

àní láti Ejibiti dé Eufurate

láti Òkun dé Òkun

àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.

13 Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀,

nítorí èso ìwà wọn.

14 Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ,

èyí tí ó ń dágbé nínú igbó

ní àárín Karmeli.

Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi

bí ọjọ́ ìgbàanì.

15 “Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá,

ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”

16 Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n,

nínú gbogbo agbára wọn.

Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn,

etí wọn yóò sì di.

17 Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò,

wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló.

Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,

wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.

18 Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀,

ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì,

tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀?

Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé

nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.

19 Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa;

òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀,

yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.

20  Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu

ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu,

bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa

láti ọjọ́ ìgbàanì.

2 Ọba 18:7–8

7 Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín. 8 Láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Filistini run, àti títí dé Gasa àti agbègbè rẹ̀.