Àwọn Ìhìnrere

Apá 1: Àwọn Orísun Àwọn Ìwé Ìhìnrere

Luku Ṣàlàyé Ọ̀nà Ìwádìí Rẹ̀

Nínú ọ̀rọ̀ ìyàsọ́tọ̀ ìwé rẹ̀, Luku ṣàlàyé ọ̀nà ìwádìí rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Luku 1:1–4

1:1 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa, 2  àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́. 3  Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ, 4  kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.