Jobu Dá Elifasi Lóhùn

2130 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jobu 6–7

1 Jobu sì dáhùn ó si wí pé,

2 “Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,

kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!

3 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,

nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.

4 Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,

oró èyí tí ọkàn mi mú;

ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.

5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,

tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?

6 A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,

tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?

7 Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,

òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.

8 “Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;

àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.

9 Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,

tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

10 Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,

àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:

nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11 “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?

Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?

12 Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?

Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?

13 Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:

ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,

kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?

15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé

bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.

16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,

àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.

17 Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,

nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

18 Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,

wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.

19 Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,

àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.

20 Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;

wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.

21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;

ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.

22 Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,

tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?

23 Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,

tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?

24 “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́

kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.

25 Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó

ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?

26 Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe

àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.

27 Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,

ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28 “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.

Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé,

ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.

29 Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;

àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.

30 Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?

Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?

7:1 “Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀?

Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?

2 Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji,

àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.

3 Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù,

òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.

4 Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’

Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.

5 Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ,

awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.

6 “Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ,

o sì di lílò ní àìní ìrètí.

7 Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;

ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.

8 Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;

ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.

9 Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ,

bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.

10 Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

11 “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,

èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,

èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.

12 Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú,

tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?

13 Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára,

ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.

14 Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi,

ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí.

15 Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa

àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.

16 O sú mi, èmi kò le wà títí:

jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

17  “Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?

Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?

18 Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,

ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkígbà!

19 Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,

tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.

20 Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ.

Ìwọ Olùsójú ènìyàn?

Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe àmì itasi níwájú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ?

21 Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn,

kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò?

Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀,

ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”