Jobu Dá Bilidadi Lóhùn: Ìpọ́njú Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Ìwà Búburú

Jobu dá Bilidadi lóhùn, ó sì sọ pé ìpọ́njú kì í ṣe ẹ̀rí ìwà búburú.

2130 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jobu 9–10

1 Jobu sì dáhùn ó sì wí pé,

2 “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́.

Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?

3 Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà,

òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọ̀rọ̀.

4 Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun.

Ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?

5 Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:

tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.

6 Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,

ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì.

7 Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,

kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.

8 Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,

ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun.

9 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari àti Orioni,

Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.

10 Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,

àní ohun ìyanu láìní iye.

11 Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i,

ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.

12 Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?

Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?

13 Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,

àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.

14 “Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé?

Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí?

15 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn;

ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.

16 Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,

èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.

17 Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,

ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.

18 Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,

ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.

19 Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!

Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?

20 Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;

bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.

21 “Olóòótọ́ ni mo ṣe,

síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi,

ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.

22 Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:

‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’

23 Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,

yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.

24 Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;

ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;

bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?

25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,

wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.

26 Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;

bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.

27 Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,

èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’

28 Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,

èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.

29 Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,

ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?

30 Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi,

tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,

31 síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò

ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.

32 “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,

tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.

33 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa

tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.

34 Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,

kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí.

35 Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;

ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.

10:1 “Agara ìwà ayé mi dá mi tán;

èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi

èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.

2 Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé, má ṣe dá mi lẹ́bi;

fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.

3 Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára,

tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú?

4 Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí?

Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?

5 Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,

ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,

6 tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi,

tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

7 Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,

kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

8 “Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi.

Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.

9 Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀.

Ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?

10 Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà,

ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?

11 Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí,

ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

12 Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere,

ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

13 “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;

èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.

14 Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi

ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.

15 Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!

Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè,

èmi dààmú

mo si wo ìpọ́njú mi.

16 Bí mo bá gbé orí mi ga, ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún

àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.

17 Ìwọ sì tún mu àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi di ọ̀tún

ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi;

àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.

18 “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?

Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.

19 Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè,

à bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.

20 Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá!

Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.

Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.

21 Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,

àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú,

22 ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀,

àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu,

níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”