Apá 7: Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ńlá ní Galili
Ó ṣeé ṣe jù lọ pé ó jẹ́ láti ìgbà ìrẹ̀dànù ewé ọdún AD 27 sí ìgbà ìrúwé ọdún 29 (ó dà bíi pé ó tó ọdún kan àtààbọ̀)
Marku sọ nípa àkókò yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, Luku sì sọ ọ́ ní ṣókí, nígbà tí Matiu gbé apá yìí kalẹ̀ ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú àwọn kókó ọ̀rọ̀. Ìhìnrere Marku bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ńlá ní Galili (fi wé àkótán ìgbésí ayé Kristi tí Peteru sọ fún agbo ilé Korneliu nínú Ìṣe àwọn Aposteli 10:36–43). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọsílẹ̀ náà mú kí pípín wọn sí àwùjọ lọ́nà tó ṣe kedere ṣòro, ṣùgbọ́n àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń tẹ̀ síwájú.
- Lẹ́yìn tí a kọ̀ ọ́ ní Nasareti, Jesu Ṣí Lọ sí Kapernaumu
- Ìrìn àjò àkọ́kọ́ káàkiri Galili pẹ̀lú àwọn apẹja mẹ́rin, àti ìpè Matiu (Lefi) nígbà ìpadàbọ̀, bí òkìkí Jesu ti ń tàn sí i.
- Àríyànjiyàn náà nípa ọjọ́ ìsinmi ní Jerusalẹmu àti Galili
- Jesu Yan Àwọn Méjìlá Ó sì Wàásù Lórí Òkè
- Ìpa Kristi Ń Pọ̀ Sí I, Johanu Sì Béèrè Láti Ẹ̀wọ̀n
- Ìrìn àjò kejì ká Galili (nísinsìnyí pẹ̀lú àwọn Méjìlá), àti ìṣọ̀tá líle àwọn Farisi.
- Àkójọpọ̀ ńlá àkọ́kọ́ ti àwọn òwe, pẹ̀lú ìbẹ̀wò sí Gerasa (Kursi) àti ìbẹ̀wò ìkẹyìn sí Nasareti.
- Ìrìnàjò kẹta káàkiri Galili (pẹ̀lú Jesu tí ó ń tẹ̀lé àwọn Méjìlá), àti ipa rẹ̀ lórí Herodu Antipa.
Jesu Kọ́ni ní Galili
Àkọsílẹ̀ gbogbogbò nípa ẹ̀kọ́ Jesu ní Galili.
27 sí 29 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
Matiu 4:17
4:17 Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Marku 1:15
1:15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
Luku 4:15
4:15 Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
Ní Kana Jesu Wo Ọmọ Ọ̀gá Kan Sàn
Ní Kana, Jesu wo ọmọ ọ̀gá kan láti Kapernaumu tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ọba sàn.
Níhìn-ín, nínú ìkọ̀sílẹ̀ ní Nasareti àti ilé tuntun ní Kapernaumu, Jesu tún ṣèbẹ̀wò sí Kana àti Nasareti, ó tún pe àwọn apẹja mẹ́rin lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Galili, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́ni àti ìwòsàn rẹ̀ ní Kapernaumu.
Johanu 4:46–54
4:46 Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. 47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.
48 Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”
49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”
50 Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”
Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. 52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”
53 Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.
54 Èyí ni iṣẹ́ àmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.
Nasareti Kọ̀ Jesu fún Ìgbà Àkọ́kọ́
Luku 4:16–31
4:16 Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. 17 A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
18 “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,
nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí
láti wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì.
Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti
ìmúnríran fún àwọn afọ́jú,
àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,
19 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”
20 Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. 21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”
22 Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”
23 Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”
24 Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. 25 Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo. 26 Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni. 27 Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.”
28 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, 29 wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. 30 Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.
31 Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.
Jesu Fi Kapernaumu Ṣe Ilé Rẹ̀
Matiu 4:13–16
4:13 Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14 Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé,
15 “Ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali
ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,
Galili ti àwọn kèfèrí.
16 Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn
tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,
àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú
ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”