Jesu Kọ́ Àwọn Ogunlọ́gọ̀ Púpọ̀ Ó sì Wò Wọ́n Sàn Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun

Jesu kọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ púpọ̀ ó sì wò wọ́n sàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Galili.

Níhìn-ín a rí Kristi tí ó ń yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá, tí ó sì ń sọ Ìwàásù Lórí Òkè fún wọn àti fún àwọn ogunlọ́gọ̀.

27 sí 29 lẹ́yìn ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Matiu 12:15–21

12:15  Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.

16 Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn. 17 Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé,

18  “Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn.

Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;

èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.

Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.

19 Òun kì yóò jà, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;

ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.

20 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,

àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.

Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìṣẹ́gun.

21 Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.”

Marku 3:7–12

3:7  Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 8  Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni. 9 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn.

10  Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló bí ara wọn lù ú láti fi ọwọ́ kàn án. 11 Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”

12  Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.

Jesu Yan Àpọ́sítélì Méjìlá

Lẹ́yìn òru àdúrà kan, Jesu yan àpọ́sítélì méjìlá.

Marku 3:13–19

3:13  Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

14 Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù 15 àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.

16  Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:

Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru),

17 Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí “àwọn ọmọ àrá”).

18 Àti Anderu,

Filipi,

Bartolomeu,

Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Taddeu,

Simoni tí ń jẹ́ Sealoti

19  àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

Luku 6:12–16

6:12  Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run.

13 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli:

14 Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀,

Jakọbu,

Johanu,

Filipi,

Bartolomeu,

15 Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Simoni tí a ń pè ní Sealoti,

16 Judea arákùnrin Jakọbu,

àti Judasi Iskariotu tí ó di ọ̀dàlẹ̀.