Jeremiah Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Lòdì sí Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Neko

Àsọtẹ́lẹ̀ Jeremiah lòdì sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Farao Neko.

606 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jeremiah 46:1–12

1  Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè.

2 Nípa Ejibiti.

Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

3 “Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,

kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!

4 Ẹ di ẹṣin ní gàárì,

kí ẹ sì gùn ún.

Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ

pẹ̀lú àṣíborí yín!

Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,

kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

5  Kí ni nǹkan tí mo tún rí?

Wọ́n bẹ̀rù,

wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,

wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.

Wọ́n sá,

wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,

ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”

ni Olúwa wí.

6 “Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,

tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.

Ní àríwá ní ibi odò Eufurate

wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

7 “Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,

tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?

8 Ejibiti dìde bí odò náà,

bí omi odò tí ń ru.

Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’

Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.

9 Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,

ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.

Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,

àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;

àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.

10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,

títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.

Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ

ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.

11 “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,

ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.

Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,

kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.

12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,

igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.

Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,

àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”

Àwọn ọmọ Rekabu Sá sí Jerusalẹmu fún Ààbò

Àwọn ọmọ Rekabu sá kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Babeli sí Jerusalẹmu fún ààbò.

Jeremiah 35

1 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé: 2 “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

3 Nígbà náà ni mo mu Jaaṣaniah ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rekabu. 4 Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. 5 Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”

6 Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé. 7 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’ 8 Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa. 9 Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn. 10 Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa. 11 Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”

12 Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13 “Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 14 ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 15 Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 16 Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

17 “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

18 Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’ 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Jonadabu ọmọ Rekabu kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”