Jeremiah Rí Ìbànújẹ́ Ìgbèkùn Ṣáájú (continued)

Jeremiah, gẹ́gẹ́ bí wòlíì, ṣàpèjúwe ṣáájú àwọn ìbànújẹ́ ìgbèkùn tí ń bọ̀.

612 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jeremiah 5–6

1 “Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu,

wò yíká, kí o sì mọ̀,

kí o sì wá kiri.

Bí o bá le è rí ẹnìkan,

tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo,

n ó dáríjì ìlú yìí.

2 Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’

síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

3 Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́?

Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n;

ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.

Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,

wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

4 Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí;

wọn jẹ́ aṣiwèrè,

nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa,

àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.

5 Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,

n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;

ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa

àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,

wọ́n sì ti já ìdè.

6 Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,

ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run,

ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín

ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,

nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,

ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.

7 “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?

Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀

àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.

Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn,

síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà

wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.

8 Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,

tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.

9 Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?”

ni Olúwa wí.

“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi

lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

10 “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,

ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá.

Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,

nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

11 Ilé Israẹli àti ilé Juda

ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,”

ni Olúwa wí.

12 Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa;

wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!

Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;

àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.

13 Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,

ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.

Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”

14 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí:

“Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí;

Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná,

àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.

15 Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí,

“Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín

Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì

àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀,

tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.

16 Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí

gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.

17 Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ,

àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin,

wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ,

wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.

Pẹ̀lú idà ni wọn ó run

ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.

18 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá. 19 Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’

20 “Kéde èyí fún ilé Jakọbu,

kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.

21  Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,

tí ó lójú ti kò fi ríran

tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.

22 Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?”

ni Olúwa wí.

“Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?

Mo fi yanrìn pààlà òkun,

èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.

Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;

wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

23 Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,

wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.

24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,

‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,

ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,

tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’

25 Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,

ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

26 “Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà

tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,

àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.

27 Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,

ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn;

wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

28 wọ́n sanra wọ́n sì ń dán.

Ìwà búburú wọn kò sì lópin;

wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.

Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.

29 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?”

ni Olúwa wí.

“Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi

lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

30 “Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara

ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.

31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,

àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn,

àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí,

kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?

6:1 “Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò!

Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.

Ẹ fọn fèrè ní Tekoa!

Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Beti-Hakeremu!

Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,

àní ìparun tí ó lágbára.

2 Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,

tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.

3 Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.

Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,

olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”

4 “Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!

Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!

Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,

ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.

5 Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́

kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

6 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀

kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.

Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,

nítorí pé ó kún fún ìninilára.

7 Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,

náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.

Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;

nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.

8 Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀,

kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,

kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,

tí kò ní ní olùgbé.”

9 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli

ní tónítóní bí àjàrà;

na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i

gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”

10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn?

Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi?

Etí wọn ti di,

nítorí náà wọn kò lè gbọ́.

Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,

wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.

11 Èmi kún fún ìbínú Olúwa,

èmi kò sì le è pa á mọ́ra.

“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro,

àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀,

àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀,

àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.

12 Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,

oko wọn àti àwọn aya wọn,

nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi

sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”

ni Olúwa wí.

13 “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju,

gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,

àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀

sì kún fún ẹ̀tàn.

14 Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn

mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.

Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’

nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.

15 Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí?

Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́,

wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú.

Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú,

a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”

ni Olúwa wí.

16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,

ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́,

ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,

ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’

17 Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,

mo sì wí pé:

‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’

ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’

18 Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;

kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí,

ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.

19 Gbọ́, ìwọ ayé!

Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,

èso ìrò inú wọn,

nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,

wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.

20 Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá,

tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré?

Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà,

ọrẹ yín kò sì wù mí.”

21 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

Àwọn baba àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,

àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”

22 Báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,

a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde

láti òpin ayé wá.

23 Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,

wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú.

Wọ́n ń hó bí omi Òkun,

bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;

wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun,

ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”

24 Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,

ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa

bí obìnrin tí ń rọbí.

25 Má ṣe jáde lọ sí orí pápá

tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà,

nítorí ọ̀tá náà ní idà,

ìpayà sì wà níbi gbogbo.

26 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,

kí ẹ sì sùn nínú eérú,

ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún

gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo

nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.

27 “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́

irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù,

kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,

kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.

28 Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn.

Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì.

Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,

wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.

29 Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan,

kí ó lè yọ́ òjé,

ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;

a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.

30 A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀,

nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”