Jeremiah Pe fún Ìrònúpìwàdà, Ó sì Ṣọ̀fọ̀ (continued)

Jeremiah rọ àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ìpọ́njú wọn bí ìgbèkùn ti ń sún mọ́lé.

612 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jeremiah 9–10

1 Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi

kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!

Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru

nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.

2 Háà, èmi ìbá ní ni aginjù

ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,

kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀

kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:

nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà

àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.

3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀

bí ọfà láti fi pa irọ́;

kì í ṣe nípa òtítọ́

ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.

Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;

wọn kò sì náání mi,

ní Olúwa wí.

4 “Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;

má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.

Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,

oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.

5 Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni

tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn

láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn

di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀

6 Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn;

wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,”

ni Olúwa wí.

7 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Wò ó, èmi dán wọn wo;

nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe?

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?

8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;

ó ń sọ ẹ̀tàn.

Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀,

ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

9 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”

ni Olúwa wí.

“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara

mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”

10 Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè

àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì.

Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀.

A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn.

Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ,

bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

11 “Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì

àlàpà àti ihò àwọn ìkookò.

Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro

tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.”

12 Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?

13 Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14 Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. 16 Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”

17 Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:

“Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá;

sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.

18 Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,

kí wọn wá pohùnréré ẹkún

lé wa lórí títí ojú wa yóò

fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa.

19 A gbọ́ igbe ìpohùnréré

ẹkún ní Sioni:

‘Àwa ti ṣègbé tó!

A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,

nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”

20 Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa;

ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún,

kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.

21 Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé

ó sì ti wọ odi alágbára wa

ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò

àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.

22 Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú

bí ààtàn ní oko gbangba

àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè

láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”

23 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀,

tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀,

tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

24  Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:

òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé,

Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́,

ìdájọ́ àti òdodo ní ayé,

nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,”

Olúwa wí.

25 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan. 26 Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”

10:1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli. 2 Báyìí ni Olúwa wí:

“Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí,

kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín,

nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè.

3 Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn,

wọ́n gé igi láti inú igbó,

oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.

4 Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.

Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó

kí ó má ba à ṣubú.

5 Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko,

òrìṣà wọn kò le è fọhùn.

Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé

wọn nítorí pé wọn kò lè rìn.

Má ṣe bẹ̀rù wọn;

wọn kò le è ṣe ibi kankan

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”

6 Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa;

o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.

7 Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ?

Ọba àwọn orílẹ̀-èdè?

Nítorí tìrẹ ni.

Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè

àti gbogbo ìjọba wọn,

kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.

8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè,

wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí.

9 Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi,

àti wúrà láti Upasi.

Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n

kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò,

èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà.

10 Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,

òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.

Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;

orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.

11 “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”

12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,

ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,

ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.

13 Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo;

ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé.

Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,

ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14 Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀,

ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀,

nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni,

kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀.

15 Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà;

nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé.

16 Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí,

nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo

àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀.

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

17 Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀

ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì.

18 Nítorí èyí ni Olúwa wí:

“Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn

àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde.

Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn,

kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”

19 Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!

Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn,

bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi,

“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”

20 Àgọ́ mi bàjẹ́,

gbogbo okùn rẹ̀ sì já.

Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́,

kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́,

tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi.

21 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè,

wọn kò sì wá Olúwa:

nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere

àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.

22 Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀,

àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá!

Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro,

àti ihò ọ̀wàwà.

23 Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀,

kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.

24 Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan

kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ,

kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.

25  Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè

tí kò mọ̀ ọ́n,

sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ.

Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,

wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá,

wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.