Apá 6: Ikú Jakọbu àti Àwọn Baba Ńlá
Jakọbu Súre fún Àwọn Ọmọkùnrin Rẹ̀, Ó sì Kú
1689 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
27 Àwọn ará Israẹli sì tẹ̀dó sí Ejibiti ní agbègbè Goṣeni. Wọ́n ní ohun ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye.
28 Jakọbu gbé ní Ejibiti fún ọdún mẹ́tàdínlógún iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹ́tàdínlàádọ́jọ (147). 29 Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Israẹli láti kú, ó pe Josẹfu, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Bí mo bá rí ojúrere ni ojú rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ejibiti. 30 Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Ejibiti kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.”
Josẹfu sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.”
31 Jakọbu wí pé, “Búra fún mi,” Josẹfu sì búra fún un. Israẹli sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé orí ibùsùn rẹ̀.
48:1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀. 2 Nígbà tí a sọ fún Jakọbu pé, “Josẹfu ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Israẹli rọ́jú dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀.
3 Jakọbu wí fún Josẹfu pé, “El-Ṣaddai, fi ara hàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi. 4 Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí o bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’
5 “Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi. 6 Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n. 7 Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata. Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu).
8 Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?”
9 Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”
Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.”
10 Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.
11 Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”
12 Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. 13 Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. 14 Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí.
15 Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé,
“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi
Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀,
Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò
mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,
16 Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,
kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.
Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi
Abrahamu àti Isaaki,
kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀
lórí ilẹ̀ ayé.”
17 Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. 18 Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”
19 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 20 Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,
“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé,
‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”
Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.
21 Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22 Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”
49:1 Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín.
2 “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu;
ẹ fetí sí Israẹli baba yín.
3 “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi,
agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi,
títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.
4 Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,
nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,
lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́
(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀).
5 “Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin—
idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.
6 Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,
kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,
wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.
7 Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀,
àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà!
Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu,
èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli.
8 “Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,
ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ,
àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.
9 Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda,
o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi.
Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,
ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?
10 Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀,
títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé,
tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un.
11 Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà,
àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.
Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì
àti ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi-pupa ti èso àjàrà.
12 Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ,
eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ.
13 “Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun,
yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi,
agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni.
14 “Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára
tí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn.
15 Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,
àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,
yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,
yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá.
16 “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
17 Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà
àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,
tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀,
kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn.
18 “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, Olúwa.
19 “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi,
ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn.
20 “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára;
yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba.
21 “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín
tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára.
22 “Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso,
àjàrà eléso ní etí odò,
tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi.
23 Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́,
wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra.
24 Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára,
ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le,
nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu,
nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli,
25 nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,
nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ
pẹ̀lú láti ọ̀run wá,
ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀,
ìbùkún ti ọmú àti ti inú.
26 Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀
ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì,
ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu,
lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀.
27 “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú;
ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ,
ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.”
28 Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i.
29 Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. 30 Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. 31 Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. 32 Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.”
33 Nígbà tí Jakọbu ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.